Ẹgbẹ awọn nọọsi ẹka tipinlẹ Ondo ti kọ jalẹ lati gba aabọ owo-osu keji, ọdun yii, eyi tijọba n gbero lati san fawọn oṣiṣẹ.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, eyi ti alaga wọn, Ọgbẹni Olomiye Kẹhinde, ati akọwe, Aina Emmanuel Oluwasẹgun, jọ fọwọ si ni wọn ti sọ pe inu awọn ko dun rara fun bi Gomina Akeredolu ṣe fẹẹ fipa san ida ọgọta pere sinu asunwọn ile-ifowopamọ awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bii owo oṣu keji, ọdun 2021, lẹyin ti awọn ti tà ko aba naa lasiko ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ati awọn aṣoju ijọba n jiroro lori rẹ.
Wọn ni imọran ti awọn ni fun ijọba Akeredolu ni pe o le ko iwọnba owo to ba wa lọwọ rẹ pamọ sibi kan na titi ti yoo fi pe odidi owo-osu kan to yẹ ko san fawọn oṣiṣẹ gẹgẹ bii owo-osu keji nitori pe ko si ninu ìpinnu awọn rara lati gba aabọ owo-osu lọwọ rẹ mọ.
Lati bii ọsẹ meji sẹyin lẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ati ijọba ipinlẹ Ondo ti n fori gbari lori ọrọ owo-osu keji sisan.
Aba tí awọn aṣoju gomina fi siwaju awọn oṣiṣẹ ni pe oun ko ni ju ida ọgọ́ta pere lọ ti oun fẹẹ san lara owo-osu keji latari owo perete ti wọn ri gba lọwọ ijọba apapọ, ṣugbọn ti awọn adari oṣiṣẹ to wa nibi ipade ọhun yari, ti wọn si ni kijọba kuku ko owo rẹ lọwọ na ti ko ba ti i pe odidi owo-osu kan.
Airi ori ọrọ yii fi ti sibi kan lati igba naa lo ṣokunfa bawọn oṣiṣẹ ko ṣe ti i ri owo oṣu keji wọn gba titi di asiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.