Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Meji lara awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo ti wọn fẹsun kan laipẹ yii pe wọn ta ọmọ obinrin ọlọdẹ ori kan lọna ti ko bofin mu ti foju bale-ẹjọ ẹjọ giga kan to wa l’Akurẹ.
Awọn afurasi mejeeji, Sarumi Adeyẹmi ati Orisamẹhin Florence Bọsẹde, ni wọn wọ lọ sile-ẹjọ ọhun lori ẹsun gbigbimọ-pọ huwa to lodi sofin ati ole jija.
Wọn fẹsun kan wọn pe wọn ji ọmọ ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Deborah Iretioluwa Ọlọrundare ti wọn si ṣe pasipaarọ rẹ pẹlu ọmọ mi-in ti ko pe lọmọ.
Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye nileesẹ to n ri sọrọ awọn obinrin ati idagbasoke awujọ ti ipinlẹ Ondo lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020.
Awọn olujẹjọ naa ni wọn lawọn ko jẹbi lẹyin ti wọn ka awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn si wọn leti.
Agbẹjọro awọn afurasi ọhun, Amofin Steve Adebọwale ati Victor Ọlatoyegun, ni wọn ti kọkọ fun awọn onibaara awọn ni beeli lori iṣẹlẹ yii kan naa ninu oṣu kẹrin, ọdun ta a wa yii, eyi ti adajọ agba nipinlẹ Ondo tẹlẹ mọ nipa rẹ.
Wọn ni o ku sọwọ ile-ẹjọ lati pinnu boya ki wọn tun ṣẹṣẹ gba beeli awọn mejeeji ni tabi ki wọn ṣi duro lori beeli ti wọn ti kọkọ fun wọn.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Adeyẹmi Fasanmi ti ile-ẹjọ giga ọhun ni oun faaye beeli wọn silẹ pẹlu miliọnu kan Naira ati oniduuro kan to jẹ onipele kejila lẹnu iṣẹ ijọba.
Ọjọ kejidinlogun, ikọkandinlogun ati ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.