Awọn oṣiṣẹ ileewe ijọba ipinlẹ Ọyọ binu si Gomina Makinde

Ọlawe Ajao, Ibadan

Bi gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣe n ṣayajọ opin ọdun kan iṣejọba rẹ, ati ọdun karun-un to ti n ṣejọba ipinlẹ ọhun bọ, bẹẹ lawọn oṣiṣẹ ileewe gbogboniṣe ati ileewe awọn olukọni gbogbo kaakiri ipinlẹ ọhun n banu jẹ nitori owo-oṣu rẹpẹtẹ ti ijọba jẹ wọn.

Ọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni Gomina Makinde n ṣe ifilọlẹ ọkan-o-jọkan awọn akanṣe iṣẹ ti ijọba rẹ ṣe lati fi ṣami ayajọ ọdun akọkọ to lo ni saa keji nipo ijọba. Lọjọ naa, lasiko kan naa, lẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ileewe Poli Ibadan (The Polytechnic, Ibadan) n fẹhonu han, wọn n ṣami ọdun kan ti ijọba ti n febi pa wọn.

Bi wọn ṣe n ṣeyi ni Poli Ibadan, ni wọn n ṣe bẹẹ lawọn ileewe giga mi-in bii Oke-Ogun Polytechnic (TOPS) Saki, Adeseun Ogundoyin Polytechnic (AOP) Eruwa, Oyo State College of Education (OYSCOED) Lanlatẹ, ati Oyo State College of Agricultural Technology (OYSCATECH), to wa niluu Igboọra.

LỌjọruu, Wẹsidee, ọhun naa lawọn oṣiṣẹ kaakiri awọn ileewe giga wọnyi ti bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta, eyi to n tẹsiwaju di ọjọ Ẹtì, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn (31), oṣu yii.

Iyanṣẹlodi ọhun ni wọn n ṣe nitori bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe jẹ wọn lowo rẹpẹtẹ, ati bo ṣe kọ lati ṣafikun owo-oṣu wọn.

Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, Alaga ẹgbẹ ASUP, Ọmọwe Kọla Lawal, sọ pe ọpọ igba lawọn ti gbe igbesẹ lati fikunlukun pẹlu ijọba ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ owo ti wọn jẹ awọn, ṣugbọn ti Gomina Makinde ko fun awọn lanfaani lati ri i.

Lara awọn nnkan ti wọn n beere lọwọ ijọba ni lati fopin si ibaṣepọ to wa laarin ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Platinum Consultant, atawọn ileewe giga ijoba ipinlẹ Ọyọ. Gbogbo owo ti awọn ileewe wọnyi ba pa wọle, ileeṣẹ Platinum Consultant, yii ni wọn lo maa n ba ijọba gba a.

Ṣugbọn ninu ibeere ti agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ wọnyi n beere lọwọ ijọba, wọn ni “ki Gomina Makinde yọwọ ileeṣẹ Platinum Consultant, kuro ninu ọrọ a n gbowo lọwọ awọn ileewe sapo ijọba, nitori iyekiye ti ileeṣẹ yii ba gba lọwọ awọn, ida mẹwaa ninu ẹ nileeṣẹ yii maa n ṣe baṣubaṣu, ti ki i de apo ijọba.

“A fẹ ki ijọba ṣafikun owo-oṣu wa pẹlu ida mẹẹẹdọgbọn (25) si ida marundinlogoji (36) iye ti a n gba tẹlẹ, ki wọn si ṣamulo ilana afikun owo-oṣu wa to ti wa nilẹ.

“Bakan naa la fẹ kijọba sọ awọn oṣiṣẹ alaabọ-iṣẹ di ojulowo oṣiṣẹ lati fopin si iṣoro aito awọn oṣiṣẹ lawọn ileewe wa gbogbo”.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ wọnyi kilọ fun Gomina Makinde, wọn ni ìkìlọ lasan lawọn n fi iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ yii ṣe, bo ba kọ lati wa nnkan ṣe sawọn ipenija awọn, nigba naa lawọn yoo ba a tẹsẹ bọ ṣokoto kan naa loju paali.

Leave a Reply