Adewale Adeoye
A n pe ọrọ ọhun lọwẹ, o n laro ninu o, bii ere, bii ere, ọrọ iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC), lawọn fẹẹ gun le l’Ọjọbọ, Wesidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, tun ti gba ọna mi-in yọ bayii.
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu lorileede yii, ‘Judiciary Staff Union Of Nigeria’ (JUSUN), naa ti tun kede pe bo ba ti d’ọjọ Wesidee, awọn paapaa maa darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ lati jọ ṣe iwọde ti wọn kede rẹ pe awọn maa bẹrẹ laipẹ yii.
Atẹjade kan ti Akọwe ẹgbẹ naa, M.J Akwashika, fi sita, ti ẹda rẹ tẹ ileeṣẹ ALAROYE lọwọ, ni wọn ti rọ gbogbo ẹka ti wọn ni lorileede yii pata pe ki wọn wa ni igbaradi feto iyanṣẹlodi naa, eyi ti yoo bẹrẹ ni Wesidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Akọwe ọhun ni, ‘Lẹyin tawọn alakooso ajọ oṣiṣẹ orileede yii ti fẹnu ko nibi ipade pataki ẹgbẹ naa kan to waye lọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn ti sọ pe kawọn ọmọ ẹgbe wọn gbogbo daṣẹ silẹ, latari bi ijọba apapọ ilẹ wa ṣe ṣafikun owo epo bẹntiroolu lai bikita ipalara to le mu wa fawọn oṣiṣẹ orileede yii. Awa paapaa ta a jẹ oṣiṣẹ kootu n sọ pe awa naa maa bẹrẹ iyanṣẹlodi tiwa ni gbara tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ba ti bẹrẹ. A n fi akoko yii sọ fun gbogbo awọn alaga ati aarẹ ẹka kọọkan pe ki wọn ri i daju pe gbogbo awọn oṣiṣẹ to ba wa labẹ wọn pata ni wọn tẹle aṣẹ naa, ki wọn bẹrẹ eto iyanṣẹlodi ọhun ni pẹrẹu, bẹrẹ lati ọjọ keje, osu Kẹfa, odun 2023 yii.
Bẹ o ba gbagbe, gbara ti olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti gba iṣakoso ijọba orileede yii lo ti kede pe ijọba oun ko ni i le sanwo iranwọ ori epo bẹntiroolu ti wọn n san fawọn oniṣowo epo bẹntiroolu mọ rara. Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, to ṣe ikede yii lawọn ileepo gbogbo lorileede yii ti yi mita wọn, ti wọn si bẹrẹ si i ta epo ni ẹẹdẹgbẹta Naira lọ soke.
Igbese Aarẹ yii lo bi ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nilẹ wa ninu pe ko ba awọn sọ ọrọ naa, awọn ko si jokoo ipade kankan lori eleyii to fi ṣe ikede ọhun. Eyi lo fa a ti wọn fi fun Tinubu ni gbedeke ọjọ meje pe ko fi yi ipinnu rẹ pada lori ọrọ owo epo bẹntiroolu naa, wọn ni bo ba kọ lati ṣe bẹẹ, awọn paapaa yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi lati ọjọ Wesidee ọsẹ yii.