Bi Tinubu ba pe mi lati ba a ṣisẹ, ma a kọkọ gba iyọnda lọwọ awọn eeyan wọnyi-Wike

Adewale Adeoye

Gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Ọgbẹni Nysom Wike, ti sọ pe ki i ṣe pe oun kan maa gba iṣẹ naa bẹẹ, iyẹn ti Aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ba pe oun lati waa ba ijọba rẹ ṣisẹ. Wike ni awọn kan wa ti oun yoo fọrọ naa lọ, toun yoo si gba imọran wọn. Lara awọn to loun yoo gba iyọnda wọn koun too le ṣe iru iṣẹ bẹẹ ni iyawo oun atawọn ọrẹ oun kọọkan ti wọn sun mọ oun daadaa.

Wike sọrọ ọhun di mimọ lakooko to n ba ileeṣẹ iroyin BBC ede Gẹẹsi kan sọrọ laipẹ yii. O ni iyawo ile oun atawọn ọrẹ kori-kosun oun kọọkan loun maa kọkọ gbe ọrọ naa ka iwaju wọn ko too di pe oun maa mọ ohun toun maa ṣe, iyẹn bi Aarẹ Tinubu ba pe oun lati waa ba a ṣiṣẹ ninu iṣakooso ijọba rẹ to wa lode bayii.

Ọrọ ti ọkunrin oloṣelu yii sọ jọ awọn eeyan loju, idi ni pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ ọhun, ko si ti i figba kankan kede pe oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ naa mọ. Eyi lo ya awọn to gbọ ọrọ rẹ lẹnu pe ṣe o fẹe ba ẹgbẹ alatako ṣise ni abi o kan n sọ bẹẹ. Bo tilẹ jẹ pe o ni Aarẹ Tinubu ko ti ba oun sọ ohun kankan to jọ mọ bẹẹ rara.

‘Ko sẹni ti ko mọ rara pe mo ṣẹṣẹ pari iṣakoso ijọba ipinlẹ Rivers tan ni, ọdun mẹjọ gbako ni mo si lo lori aleefa naa, mo fẹẹ fun ara mi ni isinmi daadaa na, ara ki i ṣokuta. Ki n tiẹ too le gbe igbesẹ kankan naa, ma a kọkọ yẹ ara mi wo daadaa na boya loootoọ, ni mo ti ṣetan lati tun gba iṣẹ ilu kankan leyin ti mo ti lo ọdun mẹjọ nipo gomina. Keeyan jẹ gomina ipinlẹ kan ki i ṣe iṣẹ kekere rara, akọ iṣẹ si tun ni pẹlu.

Leave a Reply