Adebiyi Adefunkẹ, Abẹokuta
Títì gbọnin lawọn ilẹkun kootu nipinlẹ Ogun wa bayii latari aabọ owo-oṣu tawọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ wọnyi sọ pe ijọba n san fawọn. Eyi lo fa a ti wọn fi bẹrẹ iyanṣẹlodi l’Ọjọruu, ọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun 2021.
Ninu atẹjade kan ti ajọ awọn oṣiṣẹ kootu, iyẹn Judicial Staff Union Of Nigeria (JUSUN), ẹka tipinlẹ Ogun, fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ni wọn ti kede pe kawọn oṣiṣẹ kootu kankan ma ṣe wa sile-ẹjọ l’Ọjọruu ti i ṣe ọjọ keji ikede naa. Wọn ni ki wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi pẹrẹwu titi digba ti wọn yoo tun gbọ pe iṣẹ tun ya.
Alaye ti wọn ṣe nipa iyanṣẹlodi naa ni pe ijọba ipinlẹ Ogun ko sanwo oṣu awọn pe, aabọ owo-oṣu ni wọn n san fawọn lẹyin ipade ọlọkan-o-jọkan tawọn ti jọ ṣe pẹlu ijọba, eyi ti ko si idi kankan to fi yẹ ko ri bẹẹ.
Ẹnikan to ba wa sọrọ ninu awọn oṣiṣẹ kootu l’Abẹokuta, ṣalaye pe latigba tijọba apapọ ti kede afikun owo-oṣu nijọba ipinlẹ Ogun ko ti sanwo naa pe fawọn, bẹẹ wọn n sanwo awọn ileeṣẹ pe, ni ibamu pẹlu owo-oṣu tuntun naa, ti awọn to wa lẹka igbẹjọ nikan ni wọn n ṣe mọkumọku.
Ẹ oo ranti pe o le loṣu meji tawọn oṣiṣẹ kootu fi daṣẹ silẹ kari Naijiria nibẹrẹ ọdun yii, to jẹ wọn ṣẹṣẹ pada sẹnu iṣẹ ọhun ninu oṣu kẹfa ni, iyẹn lẹyin ti wọn ba awọn gomina ṣepade lori pe awọn ko fẹ kowo awọn maa wa lọdọ ijọba ipinlẹ, ti wọn ni awọn fẹẹ wa lominra lori ọrọ owo ni, eyi toyinbo n pe ni ‘Financial autonomy’