Monisọla Saka
Igbimọ awọn lọbalọba nipinlẹ Eko, ti Ọba Rilwan Akiolu, Eleko tilu Eko jẹ adari fun ti rawọ ẹbẹ si Gomina Babajide Sanwo-Olu, lati ba wọn ya ogunjọ, oṣu Kẹjọ, sọtọ laarin ọdun, gẹgẹ bii ọjọ Iṣẹṣe.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun yii, lawọn ọba yii sọrọ ọhun, lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ awọn igbimọ ọba ati ijoye ẹlẹni mẹrinlelọgọrin ti yoo bẹrẹ eto iṣakoso ẹgbẹ wọn fun ọdun marun-un mi-in.
Awọn ọba yii ni ipa pataki ni awọn ẹlẹsin ibilẹ n ko nipinlẹ naa. Wọn ni inu awọn yoo dun ti ijọba ba le ka awọn naa si gẹgẹ bii awọn ẹsin yooku lorilẹ-ede yii, ati pe ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdọọdun, lawọn fẹ ki ijọba kede gẹgẹ bii ọjọ iṣẹṣe.
Ọba Saheed Ademọla Elegushi, ti i ṣe Elegushi ti ilẹ Ikate, nipinlẹ Eko, to sọrọ lorukọ gbogbo awọn ọba sọ pe ijọba awa-ara-wa la n ṣamulo lorilẹ-ede yii, bakan naa si ni gbogbo awọn ẹsin ri niwaju ofin.
O ni ninu kalẹnda ipinlẹ Eko ati ti ilẹ Naijiria, awọn ẹlẹsin Musulumi ati Kirisitẹni ni awọn ọjọ pataki ti wọn n ṣe ọdun wọn nibẹ, ti ijọba fọwọ si, ti wọn si maa n kede ẹ nigba ti akoko ba to, nitori naa ni ọdun Iṣẹṣe tawọn ẹlẹsin abalaye maa n ṣe ṣe gbọdọ jẹ itẹwọgba, ki ijọba si tẹwọ gba ọjọ naa.
“Ọjọ ti pẹ ta a ti n bẹbẹ pe ki ijọba faaye gba wa lati maa ṣe ọdun Iṣẹṣe. Ogunjọ. oṣu Kẹjọ. lọdọọdun la maa n ṣe e. Koda, a ti lọ sileegbimọ aṣofin ipinlẹ yii lati lọọ bẹbẹ pe ki ijọba ipinlẹ Eko ya ọjọ yii sọtọ fawa naa lati maa ṣọdun iṣẹṣe.
Ijọba alagbada la n ṣe, o si yẹ ka le maa ri ẹsin tiwa naa sin nirọrun. Awọn Kirisitẹni ati Musulumi ni awọn ọjọ ti wọn ti wọn fi n ṣọdun, bẹẹ si lo ṣe yẹ kawa naa ni tiwa naa”.
Bo ṣe sọ bayii tan, ni Ọba Oniru, Ọmọgbọlahan Wasiu, naa kin ọrọ rẹ lẹyin. O ni ipa pataki ni awọn ọba alaye n ko ninu idaabobo inu ẹmi ti wọn n ṣe fun ilu. O ni oriṣiiriṣii etutu, ni wọn yoo maa ṣe lọjọ ọdun Iṣẹṣe yii lati le fọ ilu mọ, ko si tun le daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu.
Ninu ọrọ tiẹ, gomina Babajide Sanwo-Olu ni ijọba oun ko kọyan awọn oniṣẹṣe kere, nitori oun mọ ipa pataki ti wọn n ko lori eto iṣejọba.
O ni ajọṣepọ to wa laarin awọn ọba, ijọba atawọn eleto aabo ṣe pataki fun idagbasoke ati alaafia to jọba nipinlẹ Eko. O ni nitori bi oun ṣe mọ riri wọn yii naa loun ṣe fẹẹ rọ wọn lati tubọ maa duro bii olugbala, paapaa ju lọ lori eto aabo laarin awọn eeyan ati ijọba.
Sanwo-Olu tẹsiwaju pe, lara awọn atilẹyin ati ipa takuntakun alailẹgbẹ ti wọn n ko laarin ilu, loun ri lasiko idibo sipo gomina, ti gbogbo rẹ fi lọ nirọwọ rọsẹ.
O waa n ṣeleri fun wọn lẹẹkan si i, pe ijọba oun ko ni i dawọ duro lori awọn nnkan amayedẹrun lọlọkan-o-jọkan fun awọn ọba naa.