Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Gẹgẹ bi igbiyanju tiwọn lori ọrọ ajijagba ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho, awọn ọba ilẹ Yoruba lorilẹ-ede Olominira Benin ti lawọn yoo kọwe si aarẹ orilẹ-ede naa, Ọgbẹni Patrice Talon, ki Aarẹ naa le wo ohun ti yoo ba ṣe si i.
Ninu fidio kan to gba ori ẹrọ ayelujara kan ti wọn ti sọ nipa ipade naa ni awọn ọba alaye yii ti ṣalaye pe ki i ṣe Aarẹ orileede wọn nikan ni wọn fẹẹ kọwe ọhun si, bakan naa ni wọn tun lawọn yoo kọ lẹta si minista eto idajọ, minister ọrọ abele ati olori ile-igbimọ aṣofin wọn.
Ipade kan lawọn ọba alaye yii ṣe lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, laafin Ajohoun, nilẹ Olominira Benin, lẹyin ti wọn pari ipade ọhun ni wọn fi to awọn akọroyin leti pe awọn fẹnu ko lati kọwe sawọn eeyan yii, nitori Igboho to wa lahaamọ ni Benin.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ pato ohun ti lẹta naa yoo da le lori, wọn ṣeleri pe awọn yoo jẹ kawọn akọroyin mọ abajade iwe tawọn fẹẹ kọ naa lẹyin tawọn ba fi i ranṣẹ tan.
Awọn ọba naa sọ pe bawọn ba n sọ koko iwe naa jade lai ti gbe igbesẹ rẹ, o ṣee ṣe ko ma ri itẹwọgba bawọn ṣe gbero ẹ.
Bakan naa ni Ọba Ajohoun to jẹ alaga awọn lọba lọba nibẹ sọ pe oun ko ni i fakoko ṣofo lori ọrọ yii, kiakia loun yoo gbera lọ si Cotonou lati ri i pe iwe yii tẹ awọn to yẹ lọwọ lasiko to yẹ.