Awọn ọdẹ ibilẹ ṣawari awọn Fulani to n ji awọn eeyan gbe l’Ọsẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iroyin ayọ lo jẹ fawọn eeyan ijọba ibilẹ Ọsẹ, nipinlẹ Ondo, lọsẹ to kọja yii, pẹlu bọwọ ṣe tẹ mejila ninu awọn afurasi ajinigbe to n yọ wọn lẹnu lagbegbe naa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE lori aago, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni inu igbo to wa lagbegbe oju ọna marosẹ Benin, Ọwọ si Idoani, lọwọ ti tẹ awọn afurasi naa ni nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.

O ni mẹta ninu wọn lọwọ awọn ọlọdẹ ati fijilante kọkọ tẹ lẹyin ti wọn ji ọkunrin oniṣowo kan, Kunle Agbẹyẹwa, gbe lasiko to n ṣiṣẹ lọwọ ninu isọ pako rẹ to wa n’Idoani laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee.

Lẹyin-o-rẹyin lo ni awọn ọlọpaa pẹlu iranlọwọ awọn ẹsọ alaabo ibilẹ tun ri awọn mẹsan-an yooku ko ninu igbo ti wọn fara pamọ si.

Gbogbo awọn tọwọ tẹ naa lo ni wọn ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Yatọ si ọga awọn dokita ile-iwosan ijọba atawọn oṣiṣẹ abẹ rẹ meji ti wọn ji gbe lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ to kọja, ti wọn si lo bii ọjọ marun-un ninu igbekun wọn ki wọn too raaye jajabọ, ko ju bii wakati diẹ lẹyin naa lawọn ajinigbe ọhun tun ya bo isọ pako kan laarin igboro Idoani, nibi ti wọn ti fipa ji ọkunrin oniṣowo pako ta a n sọrọ rẹ yii gbe.

Eyi lo ṣokunfa bawọn ẹsọ alaabo Amọtẹkun to wa nitosi kan ṣe ko ara wọn jọ lati lepa awọn oniṣẹẹbi ọhun, ki wọn too rin jinna.

Lẹyin wakati diẹ ti wọn ti n wa awọn inu aginju to wa lagbegbe ibi iṣẹlẹ yii lọwọ tẹ mẹta lara awọn to ji oniṣowo pako naa gbe, ti wọn si ri ọkunrin naa gba pada lọwọ wọn

Leave a Reply