Awọn ọdọ ṣewọde ni Kutọ, wọn ni ki Buhari maa lọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Iwọde ti wọn ti n kede rẹ pe yoo waye kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹ-ede yii kuku waye, o kan jẹ pe ọna ọtọ ni kaluku wọn gbe e gba ni. Ni Kutọ, l’Abẹokuta, laaarọ ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun yii, bawọn eeyan kan ṣe lọọ tẹti sọrọ Gomina Dapọ Abiọdun ni papa iṣere MKO Abiọla, bẹẹ lawọn kan naa n fẹhonu han ni Kutọ kan naa, ti wọn ni afi ki Aarẹ Buhari maa ba tiẹ lọ.

Akọle oriṣiiriṣii lawọn ọdọ to n ṣewọde naa gbe dani, eyi to hande ni ju nibẹ ni ti ‘Buhari must go’ iyẹn ni pe dandan ni ki Buhari lọ.

Orin oriṣiiriṣii lawọn oluwọde naa n kọ ti wọn fi n sọ pe Naijiria ti bajẹ, wọn ni mẹkunnu ko le da gaari ra, wọn ko rowo ra ounjẹ sinu ara wọn.

Bakan naa ni wọn sọ pe ijọba amunisin to  kan n ti awọn eeyan kan mọle fọdun pipẹ ni Buhari n ṣe, wọn ni ki Aarẹ tu gbogbo awọn to ja fun ẹtọ ọmọniyan ti wọn ko satimọle silẹ, ki wọn jẹ ki wọn maa lọ sile wọn.

Awọn oluwọde yii ko fajagbọn, bẹẹ ni wọn ko ṣe jagidijagan, orin ti wọn n kọ pẹlu awọn akọle ti wọn gbe dani ni wọn lo bii nnkan ijijagbara.

 

Leave a Reply