Awọn ọdọ juna si aafin Aree ti ilu Iree, Ọlọrun lo yọ Kabiyesi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii fidi rẹ mulẹ pe awọn ọdọ kan ti inu n bi ti ju ina sinu aafin Aree ti ilu Iree, nipinlẹ Ọṣun.

Ṣugbọn a gbọ pe ori ko ọba tuntun naa yọ nitori aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, lo lọ si irinajo, ti ko si si laafin lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Latigba tijọba ana nipinlẹ Ọṣun ti kede Ọmọọba Rapheal ̣Pọnnle gẹgẹ bii Aree tuntun ni awọn ọmọ ilu naa ti pin si meji, bẹẹ ni awọn afọbajẹ si sọ pe awọn ko lọwọ si iyansipo naa.

Koda, lẹyin ọjọ mẹta ti wọn bura fun Gomina Ademọla Adeleke lo paṣẹ pe ki wọn gbe ilẹkun aafin naa ti, ki awọn ọlọpaa si gbakoso ibẹ titi ti igbimọ tijọba gbe kalẹ lati ṣewadi iyansipo naa yoo fi fi abọ jẹ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun.

Ṣugbọn laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii, la gbọ pe awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS lọọ mu ọkan lara awọn afọbajẹ ilu naa fun ifọrọwanilẹnuwo, eyi ti a gbọ pe o tubọ bi awọn ọdọ naa ninu.

A gbọ pe bi awọn kan ṣe n dana sojuupọpo lọna Iree si Ẹripa, ni awọn kan kọja si aafin, wọn si juna si abala kan nibẹ.

Alukoro fun ajọ Sifu Difẹnsi l’Ọṣun, Kehinde Adeleke, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni bi wọn ṣe n dana sun taya ni wọn n yinbọn.

Adelele ni ko si ẹmi kankan to bọ ninu iṣẹlẹ naa, ṣugbọn alaafia ko ti i pada siluu ọhun titi asiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply