Awọn ọdọ to n ṣewọde SARS binu si MC Oluọmọ, wọn loun lo dẹ tọọgi sawọn

Faith Adebọla

Ọpọ awọn ọdọ to n ṣewọde lodi si awọn SARS ni wọn ti naka si alaga ẹgbẹ onimọto ipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ, gẹgẹ bii ẹni to da awọn tọọgi sita lati kọju ija si wọn nibi ti wọn kora jọ si ni Alausa, n’Ikẹja, niluu Eko ti wọn ti n ṣewọde. Ṣugbọn ọkunrin naa ti ni ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Oriṣiiriṣii ọrọ buruku, epe ni wọn fi n ranṣẹ si ọkunrin naa, wọn ni oun lo dẹ awọn tọọgi si awọn lati waa da iwọde ti awọn n ṣe wọọrọwọ ru.

Niṣe ni awọn eeyan naa gba ori ikanni ọkunrin yii ati tawọn ọmọ rẹ lọ, ti wọn n bu u pe awọn ọmọ tirẹ wa niluu oyinbo ti wọn n jaye ọba, awọn ti awọn wa ni Naijiria ti awọn n jiya si tun n fi ẹhonu han ta ko bi awọn ọlọpaa ṣe n pa awọn alaiṣẹ, ọkunrin yii tun waa lọọ ko tọọgi wa lati maa lu awọn, ki wọn si da iwọde naa ru.

Ọmọkunrin kan to pe ara rẹ ni Akan Bant kọ ni tiẹ pe ‘Asiko niyi lati paṣẹ fun ijọba Naijiria pe ki wọn le awọn ọmọ MC wa si Naijiria lati Amẹrika.’ Epe ti ko ṣee maa kọ soju iwe ni ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Nathan n gbe ọga onimọto naa ati gbogbo mọlẹbi rẹ ṣẹ.

Ṣugbọn ọkunrin naa ti jade o, MC Oluọmọ ni ko soootọ ninu ahesọ to gbode kan naa. Nigba to n sọrọ nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Jimoh Buhari, o ni ki awọn eeyan yee sọ ohun ti ko ṣelẹ kiri. ‘Ṣe wọn ri aṣọ ẹgbẹ onimọto lọrun wọn ni, abi ṣe MC jẹ oloṣelu ni.’

Buhari ni iyọnu lawọn SARS yii paapaa n ko ba awọn onimọto pẹlu bi wọn ṣe maa n gbowo oriṣiiriṣii lọwọ wọn. O ni yoo jẹ ohun ti ko bojumu lati waa maa ta ko awọn to n ṣe iwọde ti yoo mu opin ba iru iwa palapala yii.

Leave a Reply