Awọn ọdọ Zamfara binu, wọn gbedi dina fawọn oṣiṣẹ ọba, wọn fa fọto Buhari ya

Faith Adebọla

 

 

 

Latari iṣẹlẹ ibanujẹ to waye ọjọ Ẹti, Furaidee yii, tawọn agbebọn ya bo ileewe Government Girls Secondary School, to wa lagbegbe Jangebe, nipinlẹ Zamfara, ti wọn fi foru boju ko awọn akẹkọọ-binrin to ju ọọdunrun lọ wọgbo, awọn ọdọ agbegbe naa ti gbinaya, wọn koro oju si iṣẹlẹ ọhun, wọn si fẹhonu han gidigidi.

 

Ohun ta a gbọ ni pe niṣe lawọn ọdọ naa ya bo titi marosẹ to gba agbegbe naa kọja, wọn gbe igi ati okuta soju ọna lati di awọn onimọto lọna, wọn o jẹ ki wọn kọja, wọn si tun dana sun taya laarin titi.

Wọn ni bi wọn ti n ṣe eyi ni kaluku wọn gbe kumọ ati igi dani, ti wọn n fede ibilẹ wọn sọrọ fatafata pe awọn o fẹ iru iṣẹlẹ yii, ijọba to wa lode yii si ti ja awọn kulẹ, wọn ni kijọba ba awọn wa awọn aburo awọn ti wọn ji gbe lọ.

Wọn lawọn ọdọ naa tun ya bo awọn ọfiisi tawọn oṣiṣẹ ijọba ti n ṣiṣẹ lagbegbe naa, wọn ko si jẹ ki wọn raaye wọle tabi jade, bẹẹ ni wọn n fa awọn posita ati fọto ti aworan Aarẹ Muhammadu Buhari ba ti wa ninu rẹ ya.

A gbọ pe awọn agbofinro ti lọ sibi tawọn ọdọ naa wa lati ma ṣe jẹ ki wọn ba dukia ijọba jẹ, ṣugbọn wọn ko ti i mu ẹnikẹni titi dasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Wọn lawọn to n ṣe kara-kata lagbegbe iṣẹlẹ yii ti tilẹkun ṣọọbu wọn, ọpọ awọn obinrin atawọn olugbe ibẹ fidi mọle, inu ijaya ati ibẹru-bojo si lawọn eeyan wa bayii.

Leave a Reply