Monisọla Saka
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, ẹka teṣan Ilasan, ti tẹ afurasi mẹrin kan, nitori bi wọn ṣe wọ owo to n lọ bii miliọnu kan aabọ Naira kuro ninu akanti ẹni ti wọn fi ọkọ wọn ja lole.
Gẹgẹ bi awọn ole to n jaayan ninu mọto, ti wọn n pe ni wan ṣansi (One chance), ṣe n ṣoro kaakiri ilẹ Naijiria, lẹyin ti wọn ba lu awọn to kagbako wọn nilukulu tan, ti wọn gbowo lọwọ wọn, ni wọn maa n lọọ ja wọn si ibi to ba wu wọn.
Lẹyin ti wọn fiya jẹ obinrin yii tan ni wọn tun wọ obitibiti owo kuro ninu apo banki rẹ.
Awọn afurasi mẹrẹẹrin yii ni Michael Adeyẹyẹ, Biọdun Iyiọla, Adelẹyẹ Dọtun ati Habeeb Azeez. Ọwọ tẹ wọn lẹyin iwadii ati itọpinpin tawọn agbofinro ṣe lẹyin ti ẹni ti wọn ṣe ni jamba waa fẹjọ sun ni teṣan.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fọrọ naa lede sọ pe, “Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati teṣan Ilasan, ti fi panpẹ ofin gbe awọn afurasi wọnyi. Habeeb Azeez, ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), Michael Adeyẹyẹ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26), Biọdun Iyiọla (ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46), ati Adelẹyẹ Dọtun, toun jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27).
“Lẹyin iwadii finnifinni lọwọ ba wọn lagbegbe Ijọra-Badia, nipinlẹ Eko, lẹyin ti ẹni ti wọn ja lole waa fẹjọ wọn sun pe miliọnu kan ati irinwo Naira (1.4 million), ni awọn afurasi gba jade ninu asunwọn banki oun lasiko t’oun ṣi ọkọ wọn wọ, ti wọn ja oun lole lagbegbe Ilasan”.
Hundeyin ṣalaye siwaju si i pe bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ ko ti i da awọn afurasi lẹbi, awọn mọ-ọn-mọ ṣi oju wọn silẹ lai da nnkan bo o nitori awọn funra wọn ti jẹwọ ninu akọsilẹ ti wọn ṣe pe loootọ lawọn ṣe oun ti wọn fẹsun rẹ kan awọn.
Ati pe eleyii yoo jẹ anfaani fawọn eeyan mi-in lati da oju awọn atilaawi mọ, ki wọn ma baa ko si panpẹ wọn mọ.