Wọn ti mu Saliu to lọọ jale nile onile n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, ni awọn afurasi meji kan, Ọlarewaju Saliu ati Ayuba Saliu, wa bayii, ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe Saliu ji ẹnjinni to n fami jade ninu kanga,  to si lọọ ta a fun Ayuba.

A gbọ pe ẹrọ to n fa omi jade ninu ilẹ to jẹ ti Ọgbẹni Isiaka Tunde, to n gbe ni opopona Imam Yusuf Onímọ́sà, lagbegbe Mandate Estate, nijọba ibilẹ Ìwọ-Oòrùn Ilọrin (West), Ilọrin, ipinlẹ Kwara lo ji gbe.

Ọgbẹni Isiaka ṣalaye fun akọroyin wa pe igba keji ree ti awọn adigunjale yoo waa ji ẹrọ naa gbe laarin oṣu kan, leyii ti wọn fẹẹ ko oun si oko gbeṣe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, ṣalaye pe bi wọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti lawọn ti lọọ nawọ gan Ayuba, to ra ẹru ole naa.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti fa ọkunrin naa le awọn ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun itẹsiwaju iwadii, ati ki wọn le foju wọn ba ile-ẹjọ lati le jẹ ẹkọ fun awọn to ba tun n gbero lati hu iru iwa bẹẹ.

Adetoun rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ naa pe ki ẹnikẹni to ba kẹẹfin iwa ibajẹ laduugbo wọn kan si agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn ju lọ.

 

Leave a Reply