Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gbogbo awọn ọlọja lo ti gbogbo ṣọọbu wọn pa latari iwọde ‘June 12’ to n lọ lọwọ niluu Akurẹ ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.
Nnkan bii aago mẹjọ aarọ lawọn to fẹẹ kopa ninu iwọde naa ti pe jọ si agbegbe Old Garrage, pẹlu oriṣiiriṣii akọle lọwọ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ko kede ofin konilegbele, sibẹ ṣe lawọn opopona bii Ọba Adesida, Arakalẹ, NEPA, Hospital Road, Fiwaṣaye si Ọba-Ile, Ọda ati Alagbaka da paroparo bii ọja, ti ibẹru ko si jẹ kawọn eeyan le jade lọ sibikibi.
Iwọnba awọn eeyan ati ọkọ perete la ri ti wọn n rin loju titi nitori ibẹru ọgọọrọ awọn agbofinro to duro wamuwamu kaakiri awọn ibi to ṣe koko laarin ilu Akurẹ.
Bakan naa si lọrọ ri niluu Ondo, Akoko ati Ọrẹ, gbogbo ọja ati ṣọọbu ni wọn ti pa, ṣe lawọn eeyan fidi mọle wọn nitori ibẹru rogbodiyan to tun le ti idi iwọde naa jade.