Ko sohun to le yẹ ẹ, iwọde ‘June 12’ yoo waye-Ẹgbẹ Akẹkọọ

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ agbegbe Guusu ilẹ Naijiria, pataki ju lọ ilẹ Yoruba, ti ni ikede ti olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorileede yii, Sunday Asefon, ṣe pe awọn ti so iwọde to yẹ ko waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọla rọ, ko kan awọn rara. Wọn ni ikede yii ko si fun awọn ẹgbẹ akẹkọọ ilẹ Yoruba, nitori pe iwọde naa yoo waye gẹgẹ bi awọn ti ṣe pinnu rẹ.

Awọn akẹkọọ ẹka Zone D yii sọ pe ko si ohun to le di awọn lọwọ lati jade fun iwọde ọhun. Wọn ni o jẹ ohun ijọloju pe Sunday le kede pe ki awọn so iwọde ti awọn ti n mura rẹ tipẹ, ti awọn si ti gbaradi fun rọ.

Awọn akẹkọọ yii sọ ọ di mimọ pe olori awọn yii kede naa lorukọ ara rẹ, ki i ṣe lorukọ gbogbo ẹgbẹ akẹkọọ nitori pe ko fi ọrọ naa lọ awọn, bẹẹ ni ko bun awọn gbọ nigba to fẹẹ gbe iru igbesẹ to gbe yii.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni Asefon gbe atẹjade kan jade pe ẹgbẹ awọn akẹkọọ ti so iwọde to yẹ ko waye lori bi nnkan ṣe n lọ lorileede yii tawọn akẹkọọ fẹẹ gun le rọ. O ni eyi ko sẹyin eto aabo ilẹ wa ti ko daa, ati pe o ṣee ṣe ki awọn kan fẹẹ ja kinni naa gba mọ awọn oluwọde lọwọ, ki wọn si fi da wahala silẹ.

Ṣugbọn pẹlu bi awọn akẹkọọ yooku ṣe jade sọrọ yii, ọjọ Satide, ọla ni yoo sọ bi ohun gbogbo yoo ṣe ri.

Leave a Reply