Awọn ọlọpaa gba mọto lọwọ mi lọna eru, wọn si ta a fun ọkan lara wọn – Kọlawọle

Florence Babaṣọla

 

Ọgbẹni Elusanmi Kọlawọle fara han niwaju igbimọ to n ṣewadii iwa awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nibẹ lo si ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn ọlọpaa pẹlu bi wọn ṣe fi ọna eru gba mọto lọwọ rẹ, ti wọn si tun ta mọto ọhun fun ọkan lara wọn.

Kọlawọle ṣalaye pe, “Nigba ti asiko ifẹyinti mi lẹnu iṣẹ ku diẹ, mo ra mọto kan lati maa lo lẹyin ti mo ba fẹyinti, ṣugbọn nigba ti wọn gbe mọto yẹn de, mo ni lati da a pada tori ki i ṣe iru eyi ti mo fẹ ni.

“Ẹgbẹrun lọna okoolelugba naira (#220,000) ni wọn ta mọto yẹn fun mi, mo si ti kọkọ san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (#100,000) nibẹ fun ẹni to ni i. Nigba ti mo waa sọ pe n ko fẹ iru ẹ, wọn ni ki n wa ẹni to maa ra a lọwọ mi.

“Mo ri ẹnikan to fẹẹ ra a, emi ati ẹni to ta a fun mi tẹlẹ si gbe e lọ sọdọ ẹni yẹn. O sanwo, mo si yọ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ti mo ti san tẹlẹ nibẹ, ki ẹni to ta mọto fun mi too gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira to ku.

“Lẹyin ọsẹ diẹ ni mo deede ri awọn ọlọpaa marun-un, wọn ni Mogbọn Police Division, nipinlẹ Ogun, lawọn ti wa, ẹni to ta mọto fun mi naa tẹle wọn, wọn kọkọ lu mi lalubami ki wọn too gbe mi sinu mọto wọn laarin oru, wọn si gbe mi lọ si Zone 11, niluu Oṣogbo.

“Mo wa nibẹ fun ọjọ diẹ, wọn ni mo ta mọto tawọn ole ji, ẹsun naa si ya mi lẹnu nitori n ko mọ nnkan kan ninu nnkan ti wọn n sọ. Mo sọ fun wọn pe gbogbo iwe to yẹ ni mo gba lori mọto naa nigba ti mo kọkọ ra a, ko too di pe mo tun un ta fẹlomin-in, ṣugbọn wọn ko gba.

“Lẹyin ọjọ diẹ, wọn fi mi silẹ, ṣugbọn wọn gbe mọto yẹn lọ si Magbọn Police Station, nipinlẹ Ogun. Gbogbo igbiyanju mi lati gba a pada lo ja si pabo. Mo pada lọ si Zone 11 lati fi nnkan to n ṣẹlẹ to wọn leti.

“Ọkan lara awọn ọga nibẹ fun mi ni ọlọpaa meji lati lọ sipinlẹ Ogun ki wọn le gba moto yẹn fun mi. Nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (#100,000) ni wọn tun gba lọwọ mi fun ẹẹmeji ti wọn lọ si Ogun, sibẹ, wọn ko ri mọto yẹn gba.

“Nigba to ya ni mo gbọ pe ọlọpaa kan to n jẹ Superintendent Ayuba ti ta mọto yẹn fun ọlọpaa kan naa nibẹ. Ẹni ti mo ṣẹṣẹ ta mọto fun ko fi mi lọrun silẹ, koda, n ko ti i san owo rẹ pada tan fun un bayii tori o ni dandan ni ki oun gba owo naa pada.

“Titi donii, ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i ṣe nnkan kan lori awọn ọlọpaa ti wọn waa fiya jẹ mi lai ṣẹ, bẹẹ ni n ko ri mọto gba. Idi niyẹn ti mo fi wa, ki igbimọ yii le gba mi, ki iya yii ma jẹ mi gbe”

Alaga igbimọ naa, Adajọfẹyinti Akin Ọladimeji, sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii.

 

Leave a Reply