Ọlọpaa ti ko aadọta ninu awọn ti wọn dana sun ọja Ileepo, l’Ekoo

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ aadọta ninu awọn janduku ti wọn dana sun ṣọọbu ati ọpọlọpọ dukia ninu ọja Ile-epo, to wa lagbegbe Oke-Odo, nijọba ibilẹ Alimọshọ, nipinlẹ Eko.

Lasiko tawọn agbofinro wa sibẹ lati mu ki ohun gbogbo pada bọ sipo ni wọn tun ri inu ibi kan ti wọn n tọju obitibiti oogun oloro si, ti wọn si n ṣe kata-kara rẹ ninu ọja naa si.

Awọn aadọta afurasi yii ni wọn sọ pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan to bẹ silẹ ninu ọja naa lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, nibi ti wọn ti ba ọpọlọpọ dukia jẹ.

Lẹyin tawọn agbofinro ko awọn gidigannku yii tan ni wọn ba awọn ile onipako ti wọn n gbe jẹ lati le dẹkun iwa ibajẹ ọwọ wọn.

Niṣe ni jinnijinni bo gbogbo agbegbe Ile-Epo, Pleasure, titi de Abule-Ẹgba, ni aṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, gẹgẹ bi awọn ikọ ọmọ ita meji ṣe doju ija kọra wọn.

Awọn tọrọ naa ṣoju wọn, ti wọn ba oniroyin sọrọ ṣalaye pe ọrọ owo tẹtẹ tita lo bi wahala ọhun.

Ija ti wọn ja titi di aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn lo bẹrẹ nigba ti ọkunrin kan lati apa Ariwa orilẹ-ede yii ta tẹtẹ, to si jẹ.

Amọ nigba to de ṣọọbu to ti ta tẹtẹ yii lati gba owo ẹ, wọn ko fun un niye owo to jẹ pe. Eyi ni wọn lo bi ede-aiyede to pada di ija igboro laarin awọn mejeeji, ti ẹgbẹ awọn alatilẹyin ẹnikọọkan wọn si ba wọn fẹ ẹ loju.

Ija to pada di ti ẹlẹyamẹya, ni wọn ni pupọ ninu awọn janduku ọhun n lo anfaani ẹ lati ja awọn ọlọja lole, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi ẹ, ki wọn too pada ju ina si aarin ọja, eyi to ba ọpọlọpọ dukia jẹ.

Awọn janduku yii ko fun awọn agbofinro ti wọn kọkọ yọju sibẹ laaye lati ṣiṣẹ wọn, bakan naa ni wọn sọ pe oko ti wọn n sọ lu awọn panapana ti wọn pe ni ipe pajawiri lati waa pana ọhun ki nnkan too bajẹ jinna ko jẹ ki wọn ri iṣẹ wọn ṣe lasiko naa.

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ṣe sọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Karun-un, ọdun yii, o ni ọga ọlọpaa teṣan Oke-Odo dari awọn agbofinro lọ sibẹ lati lọọ pana aawọ to n ṣẹlẹ nibẹ.

O fi kun un pe Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Adegoke Fayọade, ti paṣẹ pe ki wọn tete foju awọn afurasi tọwọ tẹ bale-ẹjọ.

Leave a Reply