Awọn ọlọpaa ti mu Tobilọba, fidio onihooho lo lọọ ṣe leti odo Ọṣun Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin kan, Tobilọba Isaac Jọlaosho, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si King Tblack, lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun pe o ṣe fidio pẹlu ọmọbinrin to wa nihooho leti odo Ọṣun Oṣogbo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, fidi rẹ mulẹ pe lati ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, ọdun yii, ni baba kan, Amọo Awosunwọn, to n gbe lagbegbe Idilẹkẹ Temples, Atẹlẹwọ, niluu Oṣogbo, ti lọọ sọ lagọọ ọlọpaa pe oun ri Tblak leti odo naa.

Awosunwọn sọ fun awọn ọlọpaa pe ṣe ni ọmọkunrin naa wọ aṣọ bii ti awọn olubọ Ọṣun Oṣogbo, ti ọmọbinrin kan to wa nihooho duro niwaju rẹ leti odo naa, ti wọn si jọ n ya fidio.

Lẹyin to ya fidio naa tan, ṣe lo tun gbe e sori ikanni ayelujara, to si jẹ iwa to lodi si aṣa ati iṣe ilu Oṣogbo, nitori ibi ọwọ ni odo Ọṣun Oṣogbo. Latigba naa si lawọn ọlọpaa ti n wa Tblak.

A gbọ pe ọkan lara awọn ẹlẹsin ibilẹ lorileede yii, Traditional Religion Association Worshippers of Nigeria, ni Baba Awosunwọn.

Ni ti Tblak, aworan ati fidio ihooho awọn ọdọbinrin lo maa n gbe sori ẹrọ ayelujara bii fesibuuku, tuita, instagiraamu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni bayii ti wọn ti mu un, Ọpalọla sọ pe ọmọkunrin naa yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ.

@@@@@

Leave a Reply