Jọkẹ Amọri
Pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, yoo pẹ diẹ ki ilu Ibadan too le yan ọba tuntun dipo Ọba Saliu Adetunji to waja lọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun yii. Afi ti wọn ba pari ẹjọ to n lọ ni kootu lori awọn oloye Ibadan ti Ajimọbi fi jọba.
Eyi ko sẹyin bi awọn oloye Ibadan ti wọn ti figba kan gba lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde lati gbe ẹjọ kuro ni kootu ṣe tun pohun da pe awọn ko gba mọ o, ti wọn si tun gbe iwe ẹjọ mi-in dide.
Wọn ni afi dandan ki awọn maa ba ẹjọ to ti wa ni kootu lori ọrọ awọn oloye Olubadan ti Ajimọbi fun loye lọdun 2017 lọ.
Eyi foju han pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn agbẹjọro wọn ko ṣepade pẹlu agbẹjọro awọn Olubadan, lati le fẹnu ọrọ naa jona, ki wọn si gbe ẹjọ ọhun kuro nile-ejọ. Dipo igbesẹ yii, niṣe ni agbẹjọro awọn oloye Ibadan tun gbe iwe ẹjọ mi-in dide, nibi ti wọn ti pe idajọ to sọ pe ki wọn fagi le agbekalẹ ofin ati ilana to sọ wọn di ọba ti ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ nija niwaju adajọ. Ti wọn si lawọn ko fara mọ bi wọn ṣe ni ki wọn yanju ọrọ naa labẹ ile nigba ti Makinde kọkọ de ori ipo, leyii to paṣẹ pe ki awọn oloye Ibaadan naa gbagbe ade ti wọn fun wọn, ki wọn si pada sipo ti wọn wa tẹlẹ.
Ni ọsẹ meji sẹyin ni awọn oloye Ibadan yii ṣepade pọ pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde, ti wọn si gba pe ki wọn lọọ gbe ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ naa kuro, ki igbesẹ lati fi Olubadan jẹ si bẹrẹ kiakia.
Lẹyin ipade naa ni Agba-Oye ilẹ Ibadan, Rashidi Adewọlu Ladọja, ba awọn oniroyin sọrọ, nibi to ti sọ pe Lekan Balogun ni ipo Olubadan tọ si, ohun naa ni yoo si wa ni ipo naa. Bẹẹ lo fi da awọn eeyan loju pe ko si wahala kankan laarin awọn lori ipo Oubadan.
ALAROYE pe agbẹjọro fun awọn oloye Ibadan tẹlẹ, Alagba Micheal Lana, lori foonu lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lati fidi ọrọ naa mulẹ.
Ọkunrin naa ni oun ko fẹẹ sọrọ lori ibi ti ẹjọ naa n lọ nitori adajọ ile-ẹjọ ti rọ oun lati ma ṣe ba oniroyin kankan sọrọ lori ọrọ naa.