Awọn oludibo di oṣiṣẹ INEC lọna, wọn ni afi ki wọn gbe esi idibo sori ẹrọ wọn ki wọn too lọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, paapaa ju lọ, ni agbegbe ilu Ileefẹ pe ki wọn tete maa lọ si agbegbe ti wọn ti n ka ibo wọn, ki wọn lọọ duro ti ibo wọn nibẹ lati daabo bo o.

Eyi waye pẹlu bi wọn ṣe ni awọn kan n ra ibo, ti wọn ko si tun fun awọn eeyan kan lanfaani lati dibo ni awọn agbegbe naa.

Bakan naa ni awon oludibo ni agbegbe idibo ti oludije funpo PDP, Ademọla Adeleke, ti wa ti bẹrẹ si i pariwo mọ awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo pe afi dandan ki wọn gbe esi idibo naa si ori ẹrọ ajọ eleto idibo ki wọn to kuro nibudo idibo.

Ninu fidio kan to n ja ran-in lori ẹrọ ayelujara lawọn ọmọ ẹgbẹ PP yii ti n pariwo pe awọn yoo fun wọn ni data ti nẹtiwọọki ti wọn n lo ko ba ṣiṣẹ gẹgẹ bi awọn eeyan naa ṣe wi.

Niṣe ni awọn oludibo naa di awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo yii lọna, ti wọn ko jẹ ki wọn lọ nigba ti wọn ni ko si ina ti awọn fi le gbe esi idibo naa sori ẹrọ INEC.

Bẹẹ ni wọn ṣeleri lati tan jẹneretọ fun wọn.

Leave a Reply