Awọn oludije funpo gomina l’Ọṣun buwọ lu iwe adehun alaafia

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati le fi ọkan awọn araalu balẹ pe ko ni i si jagidijagan nibi idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ti a wa yii, gbogbo awọn oludije ni wọn ti bu ọwọ lu iwe adehun alaafia bayii.

Nibi eto naa, eleyii to waye niluu Oṣogbo, lọjọ Wẹsidee, ọsẹ yii, ni awọn oludije mejila ninu awọn mẹẹẹdogun ti wọn n du ipo naa ti sọ pe awọn yoo gba alaafia laaye.

Awọn oludije mẹta ti wọn ko fara han nibi eto naa ni oludije ẹgbẹ Labour, Ọnọrebu Lasun Yusuf, Dokita Akin Ogunbiyi ti ẹgbẹ Accord ati Goke Omigbọdun ti ẹgbẹ SDP.

Nibi eto naa, eyi ti National Peace Committee, labẹ alaga rẹ, Ọgagun Abdulsalam Abubakar, ṣagbekalẹ rẹ ni Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti rọ awọn oloṣelu lati huwa to tọ nipa idibo to n bọ yii.

Ọba Ogunwusi ran gbogbo awọn oloṣelu leti pe ipinlẹ Ọṣun tobi ju gbogbo wọn lọ, wọn ko gbọdọ faaye gba erongba wọn lati da wahala silẹ ninu ilu.

O ni ko ṣee ṣe fun gbogbo wọn lati gbegba oroke, ẹni kan ṣoṣo naa ni yoo di gomina, nitori naa, ki wọn ni ẹmi to n gba ohunkohun to ba ṣẹlẹ mọra lai faaye gba idaluru rara.

Alaga ajọ eleto idibo, INEC, Ọjọgbọn Mamood Yakub, sọ ni tiẹ pe ajọ naa ti ṣetan lati ṣeto idibo ti yoo gbohunjẹ fẹgbẹ gbawo bọ nipinlẹ Ọṣun.

Mamood ke si awọn oludibo lati gba alaafia laaye nitori lagbegbe ti alaafia ba ti n jọba ni idagbasoke ati itẹsiwaju ti le wa.

Biṣọọbu Mathew Hassan Kukah, ẹni to ṣoju Ọgagun Abdulsalam nibi eto naa, sọ pe gbogbo awọn araalu gbọdọ faaye gba alaafia lati jọba.

Kukah ṣalaye pe loootọ ni ọpọlọpọ nnkan ko lọ deede lorileede Naijiria lasiko yii, ṣugbọn ojuṣe araalu ni lati yan adari ti yoo kunju osunwọn, ti yoo si ni ẹmi lati sin ilu.

O ni inu n bi awọn ọmọ Naijiria, ebi n pa wọn, bẹẹ ni ọpọlọpọ n ku, ṣugbọn a ko gbọdọ sọ ireti nu. O ke si awọn oloṣelu, ori-ade atawọn oludibo lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ lati le wa ojutuu si wahala orileede yii nitori Naijiria nilo iranlọwọ gbogbo eeyan bayii.

Lara awọn oludije ti wọn fọwọ si iwe adehun naa ni ti ẹgbẹ APC, PDP, NNPP, ZLP, APP, YPP, Boot Party ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply