Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ko jọ pe wahala to n ṣẹlẹ niluu Ire lori ọrọ ẹni ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo ọba Ọmọọba Rapheal Pọnnle, ti i tan nilẹ o. Eyi ko sẹyin bi awọn ọmọ bibi ilu naa to wa nijọba ibilẹ Boripẹ, nipinlẹ Ọṣun, ṣe kọwe si igbimọ ti Gomina Ademọla Adeleke gbe kalẹ lati ṣayẹwo bi wọn ṣe yan Aree ti Ire pe awọn ko fọwọ si ọba tuntun naa, ijọba si gbọdọ paṣẹ pe ki ilana mi-in ṣẹṣẹ bẹrẹ lọtun.
Awọn eeyan naa, ti wọn kora jọ labẹ Iree Council of Elders, pẹlu Iree Progressives Association, ṣalaye fawọn oniroyin pe tọmọde-tagba ilu naa ni wọn ko fọwọ si yiyan Ọmọọba Pọnnle gẹgẹ bii ọba tuntun.
Wọn gboṣuba fun Gomina Adeleke fun bo ṣe sạgbekalẹ igbimọ ti yoo yẹ igbesẹ naa wo lati le dena wahala ati aibalẹ aya.
Nigba to n sọrọ, Aṣiwaju ilu Iree, Ẹnjinnia Adenrele Afọlabi, ṣalaye pe ọna jibiti paraku ni wọn gba yan ọba naa, o si lodi si aṣa ilu ọhun.
O ni ijọba ibilẹ agbegbe Ariwa Boripẹ lo da nikan yan Ọmọọba Pọnnle lọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lai faaye gba awọn Iwarẹfa Mẹfa ti wọn jẹ afọbajẹ lati ṣiṣẹ wọn.
Afọlabi fi kun ọrọ rẹ pe inu gbogbo awọn dun si igbesẹ ti ijọba tuntun l’Ọṣun gbe ̀lati fopin si iwa fifi ọwọ ọla gba ni loju tiṣejọba ana hu si wọn lori ọrọ Aree ti ilu Iree.
O sọ siwaju pe igbesẹ lati dabaru ọrọ to wa nilẹ ni bi awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ṣe fi panpẹ ofin mu ọkan lara awọn afọbajẹ ilu naa, Aogun ti ilu Iree, ṣugbọn ọkan awọn ko mi rara.
“O wa ninu akọsilẹ pe ilu alaafia ni Iree jẹ, a si maa n ṣafihan eleyii nigba gbogbo. Bi wọn ṣe gbe Aogun, eyi to yọri si bi awọn ọdọ kan tinu n bi ṣe juna sinu aafin jẹ nnkan to ba wa lọkan jẹ pupọ.”
Ninu ọrọ tirẹ, Aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilu Iree, Ẹnjinnia Oluwọle Taiwo, bu ẹnu atẹ lu ọna ti awọn kan gba lati yan Ọmọọba Pọnnle, o ni awọn ko fara mọ ọn, igbesẹ ọtun si gbọdọ bẹrẹ lori yiyan Aree tuntun fun ilu naa.
Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ti iyansipo ọmọọba naa waye ni wahala bẹrẹ niluu naa, ti awọn ọmọ ilu kan ni wọn ko fi tawọn afọbajẹ ṣe lasiko igbeṣẹ yiyan ọba naa.
Wahala ọrọ naa lo si fa bi awọn ọdọ kan ṣe lọọ binu sin aafin ọba naa lọsẹ to kọja.
Ki i ṣe ilu Ire nikan lawọn araalu ti n fi ẹhonu han, ti wọn si n naka abuku si igbesẹ ti ijọba Oyetọla to ṣẹṣẹ kogba sile gbe lati yan awọn ọba. Bakan naa lọrọ ri lawọn ilu bii Ikirun ati Igbajọ.