Monisọla Saka
Niṣe lawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga Yabatech, n sa asala fun ẹmi wọn ninu ọgba ileewe ọhun lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lasiko tawọn kan ya wọ ọgba ileewe naa ni nnkan bii aago mẹwaa, ti wọn si ṣeku pa akẹkọọ kan niwaju Art Complex.
Ko sẹni to mọ ohun ti ọmọkunrin naa ṣe fun wọn, bẹẹ lẹnikẹni ko le sọ boya ara wọn ni ẹni ti wọn ṣeku pa yii. Ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn yinbọn si oloogbe ọhun to fi di pe o n jẹrora, to si ṣe bẹẹ dagbere faye. Ẹni ti wọn pa yii ni wọn ni yoo jẹ ẹni keji ti wọn ti pa nigba ti saa eto ẹkọ wọn ti bẹrẹ.
Ọkan ninu awọn akẹkọọ tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, jẹ Tayọ Aina, ṣalaye pe, “Mo n lọ sinu ọgba lati kawe alẹ fun idanwo aṣekagba mi ni mo deede gburoo ibọn, lojiji ni mo gbọ gbii nilẹ, ọkunrin to wa lẹyin mi ni mo ri to ṣubu lulẹ to n japoro.
Mi o le sọ nnkan to n ṣẹlẹ ni pato, ohun ti mo ṣaa mọ ni pe awọn ọkunrin bii meji si mẹta kan duro si ọọkan ibi ti mo wa, ibọn wa lọwọ ẹni kan ninu wọn, ṣugbọn mi o mọ boya awọn ni wọn yinbọn pa a. B’emi ṣe fẹsẹ fẹ ẹ niyẹn”.
Akẹkọọ mi-in to pe orukọ ara ẹ ni Mujibat, sọ pe ọrọ ipaniyan ati ibọn yinyin ninu ọgba ileewe awọn ti n pọ lapọju, o si yẹ kawọn alaṣẹ ileewe wa nnkan ṣe si i.
O ni ọjọ ti pẹ ti ọrọ ija ati ipaniyan awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti bẹrẹ. O ni lọjọ ti ayẹyẹ igbaniwọle awọn ku ọla ni wọn paayan kan. Wọn o si ri nnkan kan ṣe si i latọjọ ti nnkan yẹn ti n ṣẹlẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o kilọ fawọn akẹkọọ lati jawọ ninu ṣiṣe ẹgbẹ okunkun. O ni ọga ọlọpaa teṣan to wa lagbegbe naa ti yọju sibi iṣẹlẹ ọhun, o si ṣalaye pe loootọ ni wọn pa akẹkọọ kan.
O fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ bayii, ati pe awọn o ni i jẹ ki eti awọn araalu di si ọrọ naa to ba ṣe n lọ.