Awọn ọmọ Naijiria yii ti gungi re kọja ewe o, egboogi oloro ni wọn n ta ni Thailand

Adewale Adeoye

Ọwọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro lorileede Thailand ti tẹ awọn ọmọ ilẹ wa meji kan, Ọgbẹni Harrison Chinonso Onyema, ẹni ogoji ọdun, ati Ọgbẹni Ogadinma Promise Onyema, ẹni ọdun mọkanlelogoji. Ẹsun tawọn agbofinro ọhun fi kan wọn ni pe wọn n ta egboogi oloro, eyi to lodi sofin ilẹ naa.

ALAROYE gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lọwọ tẹ wọn ni otẹẹli igbalode kan to wa lagbegbe Kata, niluu Karon, lorileede Thailand, nibi ti wọn n lo fun iṣẹ ti ko bofin mu yii.

Loju-ẹsẹ ni awọn agbofinro naa si ti mu wọn lọ si teṣan ọlọpaa kan to wa lagbegbe ‘Karon Police Station’, lorileede naa.

Ẹsun meji ni wọn fi kan Harrison. Akọkọ ni pe o n gbe niluu awọn pẹlu ayederu iwe, o tun n ta egboogi oloro.

Awọn alakooso ijọba orileede naa ti sọ pe laipẹ yii lawọn maa too sọ idajọ tawọn maa ṣe fawọn afurasi ọdaran ọhun fawọn araalu.

 

Leave a Reply