Jọkẹ Amọri
Ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Oke-Ogun Development Consultative Forum (ODCF) ti pariwo pe nnkan kan ko gbọdọ ṣe ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho to wa ni ọgba ẹwọn ni ilẹ Olominira Benin. Bẹẹ ni wọn rọ ijọba Naijiria ati ijọba ilẹ Benin pe ki wọn ma tẹ ẹtọ ti ọkunrin naa ni labẹ ofin mọlẹ lasiko ti igbẹjọ rẹ ba n waye.
Ninu atẹjade ti awọn ẹgbẹ to jẹ ti agbegbe ti Sunday Igboho ti wa yii kọ, eyi ti alaga wọn, Dokita Olusẹgun Ajuwọn, ati Alukoro wọn, Jare Ajayi, fi sita ni wọn ti ṣalaye pe ohun ti Adeyẹmọ n ja fun ni lati fopin si iwa irẹjẹ ti wọn n hu si ẹya Yoruba, ninu eyi ti oun paapaa ti wa.
‘Ija to n ja jẹ nnkan idunnu ati iwuri fun wa pe o jẹ erongba rẹ lati ri i pe wọn ko da awọn agbẹ lọna, bẹẹ ni wọn ko di wọn lọwọ lati lọ sinu oko wọn. Bakan naa ni wọn ko maa fipa ba awọn obinrin wa sun lasiko ti awọn naa ba n wa jijẹ-mimu wọn kaakiri.’
Ẹgbẹ yii ni awọn ko lodi si pe ki ijọba ba awọn ti wọn ba ro pe wọn ṣẹ sofin ṣẹjọ, ṣugbọn bi wọn ba fẹẹ ṣe e naa, wọn gbọdọ ṣe e lai kọja ofin to sọ pe ẹnikẹni ti wọn ba mu fun iwa ọdaran kan ko ti i di ọdaran, afi ti ile-ẹjọ ba da a lẹbi. Bakan naa ni wọn tun ni ki ilẹ Naijiria ati orileede Benin ranti ofin ajọṣepọ agbaye to wa laarin wọn, iyẹn ofin ECOWAS to so gbogbo orileede Afrika pọ, eyi ti awọn mejeeji jọ buwọ adehun lu lati tẹle.
Wọn ni ki wọn ranti pe ninu ofin naa ṣalaye pe wọn ko le da ẹnikan pada si orileede to ti sa wa si ọdọ wọn to ba ṣe pe ọrọ to jẹ mọ oṣelu tabi ki wọn maa gbiyanju lati fiya jẹ ẹ nitori ẹya to ti wa lo tori rẹ sa wa.
Ẹgbẹ ODCF ni gbogbo awọn nnkan wọnyi lo wa ni abẹ ofin ti Naijiria naa jẹ ọmọ ẹgbẹ yii. Wọn fi kun un pe Emir Muri, nipinlẹ Taraba, paapaa kin ohun ti Sunday Igboho n sọ lẹyin ni ọsẹ to lọ lọhun-un.
Eyi ko sẹyin bi ọba alaye naa ṣe fun gbogbo awọn Fulani darandaran to wa ni agbegbe rẹ ni ọgbọn ọjọ pere lati ko angara wọn kuro ni agbegbe naa nitori ewu ti wọn fi n wu awọn agbẹ atawọn obinrin to n gbe awọn agbegbe ti kabiyesi wa yii.
‘A si gbọ pe awọn Fulani darandaran naa ti kan si ọba yii lọjọ keji, oṣu kẹjọ yii, pe awọn yoo ṣe gẹgẹ bii aṣẹ ti ọba na pa.
‘Ko si iyatọ ninu ohun ti Sunday Igboho n ja fun ati ohun ti Emir Muri yii ṣe. Nidii eyi, a gbagbọ pe ohun to ba daa fun ọtun gbọdọ daa fun osi.
‘Labẹ ofin la ti n beere fun aabo lori ara wa, lori awọn eeyan wa ati lori Sunday Igboho awọn eeyan wa ominira.’ Awọn ọmọ ẹgbẹ ODCF lo sọ bẹẹ