Ijiya nla wa fẹni to ba gba ọdaran si otẹẹli rẹ ni Kwara-Ijọba

 Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ iṣejọba Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, ti ṣe ikilọ fun gbogbo awọn to ni ileetura nipinlẹ naa, lati mọ ṣe gba awọn ọdaran laaye lawọn ileetura wọn, lati maa hu awọn iwa aitọ bii fifa egboogi oloro, ayẹyẹ onihoho ṣiṣe ati awọn iwa to ta ko ofin miiran lawọn ileetura wọn ni ipinlẹ Kwara.

Akọwe agba lẹka eto ibanisọrọ ni Kwara, Hajia Rabiat Abdulrahman, lo fi ọrọ naa lede lasiko to n ṣe abẹwo si awọn ileetura kan niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, o ṣe ikilọ pe eyikeyii ileetura ti ijọba ba gba mu to n gba iwa aitọ laaye nileetura rẹ yoo fimu kata ofin ijọba. Bakan naa ni o tun rọ wọn lati maa tẹle ofin ati ilana ti ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun nilẹ yii gbekalẹ lati dena itankalẹ arun Korona nipinlẹ Kwara.

Akọwe ọhun waa gboriyin fun iṣejọba Gomina Abdulrazaq pẹlu bo ṣe n ṣe atilẹyin fun awọn onileetura ni Kwara, to si n mu ki awọn ileeṣẹ maa pọ si i, to si n fun awọn ọdọ to niṣẹ lọwọ ni anfaani lati maa ri iṣẹ ṣe. O fi kun un pe ijọba yoo tubọ maa pa kun ilakaka awọn ileetura nipinlẹ Kwara, ki wọn le maa peṣe iṣẹ lọpọ yanturu fun awọn ọdọ to n fẹsẹ gba igboro kiri.

Leave a Reply