Awọn ajinigbe n beere aadọta miliọnu lori mọlẹbi kan ti wọn ji gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Miliọnu lọna aadọta naira ni awọn ajinigbe to ji mọlẹbi kan gbe, ti wọn si ti pa ọkọ n beere fun bayii. Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja, ni wọn pe awọn mọlẹbi naa lati fi to wọn leti pe ti wọn ba ṣi fẹẹ ri awọn eeyan wọn, afi ki wọn wa owo naa wa lai fakoko ṣofo.

Ẹnikan to sun mọ awọn mọlẹbi yii lo ṣalaye ọrọ naa fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe awọn ajinigbe naa kan sawọn mọlẹbi lọjọ Aiku, Sannde, ti wọn si beere fun iye owo naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni wọn da awọn mọlẹbi naa lọna ni oju ọna to lọ lati ilu Ewu-Ekiti si ilu Ido.

Bi awọn agbebọn bii marun-un ṣe da mọto SUV alawọ funfun ti wọn wa ninu rẹ duro ni wọn ko wọn ni papamọra, ti wọn si yinbọn fun ẹni to wa ọkọ ọhun ti wọn pe ni olori ẹbi naa. Nitori ọkunrin to jẹ ọkọ yii, iyawo rẹ pẹlu ọrẹ iyawo kan la gbọ pe wọn jọ wa ninu mọto yii. Lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn ko awọn to ku wọnu igbo lọ.

Ibi inawo kan ni Ido-Ekiti, nijọba ibilẹ Ido/Osin ni wọn ti n bọ, ti wọn si n pada si ibi ti wọn ti wa.

A gbọ pe niṣe ni wọn fi ọkọ naa silẹ ni ẹgbẹ titi, pẹlu oku ọkunrin to wa mọto naa.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa ati sifu difẹnsi pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn Amọtẹkun ti wa ninu igbo agbegbe naa, ti wọn si n gbiyanju lati doola awọn ti wọn ji ko ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ọdun yii ni awọn agbebọn yii kan naa ṣe akọlu si Ọba Adetutu Ajayi to jẹ ọba ilu Ilejemeje.

Bakan naa, ni ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ọdun yii, naa ni awọn agbebọn yii ko awọn oṣiṣẹ ileetura kan ni ilu Ayetoro, ti wọn si ṣe awọn ẹṣọ ileetura naa ṣakaṣaka.

Leave a Reply