Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ọmọ ilu Rẹmọ, ti i ṣe ilu abinibi Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, labẹ ẹgbẹ ti wọn n pe ni ‘PYO for President’ ti ni ki Igbakeji Aarẹ ile wa yii maa bọ waa dupo aarẹ Naijiria lọdun to n bọ, wọn ni gbogbo ara lawọn fi ṣatilẹyin fun un.
Ipinnu pe ki Ọṣinbajo waa dije dupo aarẹ yii ko deede waye, nibi ipade kan ti wọn ṣe pẹlu gbogbo awọn ọmọ Rẹmọ lọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun 2022 yii, n’Iṣara Rẹmọ, ni wọn ti fẹnu ko si i pe ki Yẹmi Ọṣinbajo to jẹ ọmọ awọn naa dara pọ m’awọn to fẹẹ dije dupo aarẹ ilẹ wa lọdun to n bọ.
Ọnarebu John Ọbafẹmi to ti jẹ alaga ijọba ibilẹ Ariwa Rẹmọ fun igba meji ri, to tun jẹ alaga ALGON ri lo n dari awọn ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Ọṣinbajo ni Rẹmọ naa.
Ẹgbẹ naa ṣalaye pe awọn n pe ọmọ bibi ilu Ikẹnnẹ Rẹmọ yii pe ko waa dije, nitori awọn mọ pe o ni ọgbọn inu ati oye to le fi tu ọkọ Naijiria yii de ebute ogo.
Wọn ni fun idi eyi lawọn ṣe n pe fun atilẹyin awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria gbogbo, pe kawọn naa ti Ọṣinbajo lẹyin ko le ṣee ṣe fun un lati di aarẹ ni 2023.
Diẹ ninu awọn eeyan nla to wa nibi ipade naa ti wọn wa lati ijọba ibilẹ mẹtẹẹta ti Rẹmọ pin si ni, Ọnarebu John Ọbafẹmi, Ọtunba Fatai Ṣowẹmimọ, Ọmọọba Micheal Adesanya, Alaaji Aṣiru, Ọnarebu Erinfọlami, Ọnarebu Deji Ṣolaja ati bẹẹ bẹẹ lọ.