EFCC lọọ jalẹkun ile awọn ọmọ yahoo loru, lawọn yẹn ba kọju ija si wọn l’Ọṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọrọ di bo o lọ o ya lọna laaarọ ọjọ Iṣẹgun lagbegbe Lameco, kọja si Oke-fia, niluu Oṣogbo, lasiko ti awọn ọmọ Yahoo ti wọn to ọgọrun-un fọn soju titi pẹlu onuruuru nnkan ija lọwọ wọn.

Wọn dana sun taya, bẹẹ ni wọn wọ oriṣiiriṣii nnkan soju popo, ti gbogbo awọn onimọto ti wọn n gbe awọn ọmọ lọ sileewe atawọn onikorope si n lọri pada sẹyin.

Ohun ti a gbọ ni pe ṣe lawọn ajọ to n gbogun ti jibiti ori ẹrọ ayelujara, Economic and Financial Crimes Commission, lọ sile awọn kan laago kan aabọ oru, ti wọn si jalẹkun wọle.

Bi wọn ṣe ja geeti awọn ile kan pẹlu okuta, ni wọn yọ bulọọku ferese awọn kan wọle, ti wọn si n ko wọn sinu mọto, bẹẹ ni wọn gba mọto wọn.

Idi niyẹn tawọn ọmọ Yahoo ọhun fi pe ara wọn jọ, ti wọn si lọọ dana soju ọna ti wọn yoo gba kọja. Pẹlu ibọn, igi, ada, okuta ati bẹẹ bẹẹ lọ lawọn ọdọ naa fi koju awọn EFCC.

Nigba tawọn EFCC ri i pe ọrọ naa kọja agbara, wọn fi diẹ silẹ lara awọn mọto ti wọn gba, wọn si sa lọ pẹlu mọto diẹ ti wọn fi gbe awọn ọmọ ti wọn ko.

Awọn ọdọ naa pejọ si Freedom Park, ni Old Garage, ariwo ti wọn n pa ni pe kijọba Ọṣun lọọ gba awọn ara wọn ti EFCC ko lọ ti wọn ko ba fẹ wahala nla niluu Oṣogbo.

A gbọ pe ijọba ti ran Kọmiṣanna fọrọ ọdọ ati ere idaraya, Yẹmi Lawal, lọ si ọfiisi awọn EFCC lati le wa ojutuu si ọrọ naa.

Leave a Reply