Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni adajọ ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, sọ pe ki awọn ọlọpaa lọọ ju awọn ọmọ Yahoo-Yahoo mẹrin kan, Alabi Oluwaṣeyi, ẹni ogun ọdun, Abọlarin Ṣeyi Ọlamide, ẹni ọdun mọkanlelogun, Ọladẹjọ Okikiọla, ẹni ọdun mọkandinlogun, ati Kẹhinde Ajayi, ẹni ogun ọdun, sọgba ẹwọn titi tigbẹẹjọ yoo fi tun waye lori ẹjọ wọn lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe ṣe ni wọn lọọ gba yara ni otẹẹli kan lagbegbe Garaji Ọffa, niluu Ilọrin, ti wọn si n fa oogun oloro kan ti wọn n pe ni “methamphetamine” to maa n jẹ ki awọn ti wọn ba mu un ṣiwa-hu.
Agbefọba, Zaccheus Fọlọrunsọ, sọ fun ile-ẹjọ pe awọn eroja ti awọn afurasi n fa yii, eefin rẹ le ṣe akoba fun ilera awọn araadugbo, fun idi eyi, ki adajọ sọ wọn sẹwọn titi ti iwadii yoo fi pari lori iṣẹlẹ naa.
Onidaajọ AbdulRaheem Bello, ko tiẹ gbọrọ kankan lẹnu awọn afurasi ọdaran naa to fi sọ pe ki awọn ọlọpaa lọọ ju u sẹwọn titi ti igbẹjo yoo tun fi waye lori ẹjọ wọn lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.