Awọn ọmọ Yoruba rẹpẹtẹ ya bo kootu Benin, nibi ti wọn ti fẹẹ gbọ ẹjọ Sunday Igboho

Faith Adebọla

Ni deede aago mẹrin kọja iṣẹju marun-un ni wọn ṣilẹkun ile-ẹjọ fun awọn alatilẹyin ajafẹtọọ ọmọ Yoruba  nni, Sunday Igboho. Ẹnikan to wa nibi ti igbẹjọ naa ti n lọ lọwọ to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe bi oun ṣe n sọrọ yii, awọn ti wa ninu kootu, awọn si n duro de ki wọn mu Sunday Igboho wọle ki wọn si bẹrẹ igbẹjọ naa.

Ọkunrin ti ko fẹ ka darukọ rẹ yii ṣalaye fun akọroyin wa pe ọpọ awọn to waa ṣatilẹyin fun ajijagbara ọmọ Yoruba yii ni ko raaye wọle, nitori ero ti pọ ju. Bii ẹẹdẹgbẹta awọn ọmọ Yoruba, to fi mọ awọn ọba Yoruba to wa ni ilẹ Olominira Benin ni wọn waa ṣatilẹyin fun Sunday Igboho ni kootu.

Ọkunrin naa ni adura ni awọn n gba bayii ki Ọlọrun jẹ ki ohun gbogbo lọ bi awọn ṣe fẹ.

Leave a Reply