Awọn ọmọọṣẹ Tinubu bẹrẹ ipolongo ibo aarẹ ọdun 2023 lorukọ rẹ

Jide Alabi

Awọn oloṣelu kan ti wọn jẹ ọmọ ẹyin Bọla Tinubu ti bẹrẹ ipolongo fun ọkunrin oloṣelu yii lori bi yoo ṣe di aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn ti gbe eto ọhun kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nigba ti ẹni to ṣaaju wọn,  Sẹnetọ Adedayọ Adeyẹye, lati ipinlẹ Ekiti, ko awọn yooku sodi lọ sọdọ Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji. Bakan naa ni wọn de ọdọ Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Atanda Adeyẹmi, ohun ti wọn lọọ ri awọn Ọba yii fun ni lati fi erongba wọn han lori bi wọn ṣe fẹẹ ṣiṣẹ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti yoo fi di aarẹ Naijiria lọdun 2023, bẹẹ gẹgẹ ni wọn tun bẹbẹ fun atilẹyin ati adura wọn.

Bo tilẹ jẹ pe Bọla Tinubu funra ẹ paapaa ko ti i bọ sita gbangba lati sọ pe oun yoo dupo aarẹ, sibẹ, oye ti foju han ketekete bayii pe gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko nifẹẹ si ipo ọhun gidi gan-an ni.

Lara awọn oloṣelu ọmọ ẹyin Bọla Tinubu ti wọn jọ n lọ kaakiri bayii ni Musiliu Ọbanikoro; oun ni wọn fi ṣe alaga ikojọpọ wọn, eyi ti wọn pe orukọ ẹ ni SWAGA (The South-West Agenda), awọn mi-in tun ni, Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, Sẹnetọ Adesọji Akanbi, ẹni to n ṣoju fawọn eeyan Guusu ipinlẹ Ọyọ; ẹlomi-in tun ni Ọtunba Abayọmi Ogunnusi.

Ninu ọrọ Adeyẹye, o sọ pe, “Gẹgẹ bi oye ṣe foju han bayii pe kaluku lo n sọ nipa bi ọrọ oṣelu yoo ṣe ri lọdun 2023. Bo ṣe wa ri yii, awa naa ni ipa ti a gbọdọ ko lati sọ ohun ta a fẹ gan-an nipa bi eto oṣelu yoo ṣe ri lọdun naa. Bọla Tinubu lawa nifẹẹ si gẹgẹ bii aarẹ, iṣẹ si ti bẹrẹ bayii, bẹẹ la ti kan si i ko waa dije dupo ọhun, eyi naa lo si mu wa ke si gbogbo awa ọmọ Yoruba pata ati Naijiria lapapọ lati tẹle ọkunrin oloṣelu to rẹsẹ fi tilẹ daadaa yii, ki Naijiria le tẹsiwaju.

“Gbogbo awọn eeyan to wa ni Iha Guusu orilẹ-ede yii lo lanfaani lati fa ẹni yoowu to ba wu wọn kalẹ, ẹni to ba si tẹwọn ju naa ni gbogbo ọmọ Naijiria yoo tẹle.’’

Ikuforiji ninu ọrọ tiẹ sọ pe, “Oloṣelu bii Aṣiwaju Bọla Tinubu ṣọwọn, oun yii lo sọ Eko dọtun, paapaa fawọn to mọ ipo ti ipinlẹ Eko wa ṣaaju ọdun 1999. Ipo ti Eko wa loni-in yii, Bọla Tinubu ni o. Oun yii lo sọ ipinlẹ Eko di amuyangan nla fun gbogbo ọmọ Naijiria loni-in. Ati pe ti a ba n sọ nipa ọjọ ọla to dara fun Naijiria yii, Bọla Tinubu gan-an lo ṣe e tẹle to ba di ọdun 2023.’’

Bo ṣe wi i yii, bẹẹ lawọn eeyan ipinlẹ Ọsun naa lawọn mọ riri ẹ, bakan naa lawọn eeyan ipinlẹ Ogun naa sọ tiwọn. Ohun tawọn eeyan si n sọ bayii ni pe dajudaju, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti bẹrẹ ipolongo ibo lati di Aarẹ Naijiria lọdun 2023, ko si si aniani kankan nibẹ mọ.

 

Leave a Reply