Awọn ọmọọta sọna si reluwee to n lọ si Kano niluu Ọffa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ibẹrubojo gbilẹ ni ibudokọ oju-irin ilu Ọffa, nipinlẹ Kwara, nigba ti ero kan ti wọn o mọ sọna si ọkọ oju-irin to ko ero ati ẹru to n bọ lati ipinlẹ Eko, to n lọ si ipinlẹ Kano.

ALAROYE gbọ pe ijọba ibilẹ Ọffa, niṣẹlẹ kayeefi naa ti waye, nigba ti wọn ni sadede ni ẹnikan ti wọn ko mọ, mọ-ọn-mọ juna si ọkọ oju-irin ọhun, to si fẹsẹ fẹ ẹ. Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe bi ina ṣe bẹrẹ si i jo lalaala lo ti na papabora.

Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Hakeem Adekunle, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe ọpẹlọpẹ ileeṣẹ naa to tete gunlẹ sibi iṣẹlẹ ọhun ni ko jẹ ki ina ba nnkan jẹ kọja bo ṣe yẹ. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ọkọ ojú irin ọhun lo dẹnukọlẹ, ti wọn si n ṣe atune rẹ lọwọ ni ẹnikan sadede ṣana si ọkọ naa, to si finu-fẹdọ ju ina si i ni, tawọn si pa ina naa to ku raurau, ṣugbọn ina ti mu abala meji ninu mẹwaa ninu ọkọ naa.

Adari agba ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, ti waa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati maa pe ajọ panapana lasiko ti ina ba n sọṣẹ ni agbegbe wọn ki wọn le maa doola ẹmi ati dukia awọn olugbe ipinlẹ naa.

Leave a Reply