Awọn ọrẹ meji yii rawọ ẹbẹ sijọba: A ti ronupiwada, a ko ṣẹ Boko Haram mọ, ẹ dariji wa

Adewale Adeoye

Meji lara awọn ojulowo ọmọ ẹgbẹ Boko Haram to n doju ija kọ awọn araalu nigba gbogbo ti lawọn ko ja mọ o, pe ki ijọba orileede yii siju aanu wo awọn, ki wọn da awọn naa pọ mọ ọmọ tọ gẹgẹ bi wọn ṣe ti ṣe fawọn to ti ṣaaju awọn tẹlẹ.

Awọn afunrasi ọdaran meji ti wọn ṣẹṣẹ juwọ silẹ ọhun ni: Adam Muhammad, ẹni ọdun mejidinlogun, ati Ahmed Isiaka, ẹni ọdun mẹtadinlogun, ti wọn jẹ ọmọ agbegbe Kolloram, nijọba ibilẹ Kukawa, nipinlẹ Borno.

ALAROYE gbọ pe ojulowo ọmọ ẹgbẹ Boko Haram lawọn meji ọhun ko too di pe wọn juwọ silẹ bayii, ko si iru iṣẹ laabi tawọn meji naa ki i ba awọn olori wọn ṣe nibẹ.

Yatọ si pe wọn juwọ silẹ fawọn ṣọja ilẹ wa, wọn tun ko awọn ohun ija oloro gbogbo ti wọn n lo silẹ fawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede Naijiria lati fi han pe awọn ko ṣe mọ loootọ.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii kede pe meji lara awọn olori ẹgbẹ Boko Haram kan ti waa kede pe awọn ko ṣiṣẹ laabi ọhun mọ, ti wọn si gba wọn pada saarin ilu loju-ẹsẹ.

Leave a Reply