Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti pariwo sita bayii pe awọn janduku kan tun ti n gbero lati da wahala silẹ nipinlẹ Ọṣun ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Kọmisanna feto iroyin, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita lo ti ke si obi, alagbatọ, pẹlu awọn araalu lati ki awọn ọmọ wọn bọ abẹ.
O ni aṣiri ti tu sijọba lọwọ pe awọn ọta alaafia fẹẹ lo awọn janduku naa lati tun fi awọn araalu sinu inira lẹẹkeji.
Ẹgbẹmọde fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ti fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti lati le daabo bo ẹmi ati dukia araalu nitori ina eyi to ṣẹlẹ sẹyin ko ti i ku tan.
O ni ẹnikẹni to ba kora jọ nibikibi tabi to dara pọ mọ awọn to ba kora jọ lai mọ nnkan ti wọn n ṣe yoo foju wina ofin.