Awọn ti a mu nibi iwọde Yoruba Nation ree o – Ọga ọlọpaa Eko

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ṣe afihan awọn eeyan mọkandinlaadọta kan loni-in ọjọ aiku, Sannde, pe awọn ti awọn mu nibi iwọde Yoruba Nation ti wọn ṣe lanaa niyi. O ni ni ibudo ominira ti Gani Fawẹhinmi to wa ni Ọjọta lawọn ti ko gbogbo wọn.

Odumosu ni nitori pe awọn eeyan naa ṣe ohun to tapa si ofin to lodi si ipejọ tabi iwọde kankan lEkoo lawọn ṣe ko wọn. Okunirn ọga ọlọpaa naa ni:

“Ohun ti mo ṣe pe ẹyin oniroyin jọ bayii ni lati foju awọn ti a mu nibi ti wọn ti n ṣewọde Oodua Nation lanaa Satide han yin ni. Ijọba ipinlẹ Eko ati ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ yii lodi si iwọde kankan lasiko yii, a si ti sọ bẹẹ fun gbogbo wọn tẹlẹ. A ti sọ fun wọn tẹle pe ki wọn ma wa rara, nitori Eko ko tun le faaye gba iwọde mi-in, lẹyin wahala ti oju wa ri lasiko iwọde ti EndSars!

“Ṣugbọn awọn kan wa lati da wahala silẹ, wọn ko ara wọn jọ sibẹ, iyẹn naa lo si jẹ ka mu wọn. Bi a ti mu wọn yii, ẹka to n ri si ọrọ awọn ọdaran iru eyi to wa ni Panti ni Yaba la o ko wọn lo, ki wọn le mọ iru ẹjọ to tọ si wọn lati ba wọn  ṣe lẹyin iwadii!”

Leave a Reply