Awọn to n ṣonigbọwọ fawọn agbebọn, Boko Haram ni Buhari n ṣatilẹyin fun- Fayoṣe

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ri, Ọgbẹni Ayọdele Fayoṣe, ti kilọ fawọn ọmọ orileede yii pe pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, afi konikaluku maa ṣọ ibi to maa rin si bayii, tori o ti foju han gbangba pe ijọba apapọ, ileeṣẹ aarẹ, lo n gba awọn afurasi agbebọn ati apanilaya siṣẹ, ti wọn si n gbeja wọn.

Fayoṣe ni ọrọ naa kọọyan lominu gidi, pe ileeṣẹ Aarẹ le maa yan iṣẹ fawọn afẹmiṣofo Boko Haram, atawọn janduku agbebọn, ti wọn si tun funjaa mọnu lati gbeja wọn tawọn eeyan ba sọrọ nipa ẹ, tori naa, imọran oun ni pe kawọn eeyan ṣọra ṣe, ki wọn mọ ibi ti wọn maa maa rin si, ki wọn ma si ko sakolo awọn eeyan keeyan afẹmiṣofo yii.

Fayoṣe sọrọ yii ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹẹ ẹ feto iroyin rẹ, Ọgbẹni Lere Ọlayinka, fi lede lori awuyewuye to n lọ nigboro latari bi ileeṣẹ Aarẹ ṣe lawọn o ni i gbaṣẹ lọwọ minisita feto ibanisọrọ, Ọgbẹni Isa Pantami, tijọba tun n gbeja ọkunrin naa lodi si bawọn eeyan ṣe ni kijọba yọ ọgbẹni naa nipo lo daa.

O ni “Ọrọ yii tu tubọ tu aṣiri abosi ati iwa agabagebe tijọba n hu, o kọ ni lominu, o si ba ni ninu jẹ pe awọn agbẹnusọ ileeṣẹ Aarẹ funra wọn ni wọn n lọ soke sodo kaakiri awọn ileeṣẹ agberoyinjade lati dasọ bo ẹni ti gbogbo aye ti gbọ bo ṣe sọrọ ṣatilẹyin fawọn afẹmiṣofo.

“Laarin ọjọ mẹta pere sasiko yii, o ju ọọdunrun (300) ọmọ Naijiria lọ, ti wọn da ẹmi wọn legbodo kaakiri orileede yii, tawọn mi-in si ṣi wa lakolo awọn ajinigbe, ṣe eleyii o to ki Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn eeyan ẹ daṣọ ọfọ bora, ki wọn ku eeru sori lati fi ibanujẹ wọn han ni. Ṣugbọn kaka ki wọn ṣe iyẹn, niṣe ni wọn n ṣe faaji famia niṣo bii pe nnkan kan o ṣẹlẹ.

O niṣe lawọn to n dari Naijiria yii, paapaa awọn tijọba apapọ, wọn n ṣe bii ẹni pe awọn lawọn ni orileede yii, wọn ti gbagbe pe orileede atawọn eeyan inu rẹ lo ni ijọba.

O ni ẹdun ọkan gbaa lo jẹ pe awọn ti wọn n ṣonigbọwọ fawọn agbebọn, awọn ti wọn n dunaa-dura pẹlu Boko Haram, awọn yii kan naa lo wa nipo aṣẹ ijọba, ti wọn n gbeja Boko Haram atawọn janduku agbebọn.

“Ọrọ aabo ti waa mẹhẹ debii pe gbogbo awọn oju ọna wa lawọn agbebọn, ajinigbe atawọn afẹmiṣofo ti n da awọn arinrinajo lọna, ọrọ naa ti pinyẹnkẹn debii pe inu yara lo ku ti wọn n wọ lọọ ji ọba alade gbe lori ibusun ẹ.”

Nipari, Fayoṣe ni ko sohun to yẹ kawọn eeyan ṣe lọdun 2023 ju ki wọn juwe ọna ita fẹgbẹ oṣelu APC atawọn onṣejọba rẹ lọ, tori aṣiṣe nla ni wọn ṣe lati dibo fun wọn.

Leave a Reply