Awọn to n fehonu han lori SARS kọ lu Gomina Oyetọla l’Ọsun, wọn ba gbogbo ọkọ rẹ jẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wahala nla lo n ṣẹlẹ lọwọ niluu Oṣogbo bayii pẹlu bi awọn to n fẹhonu han lori ọrọ SARS ṣe kọju ija si gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla.

Awọn ọdọ yii ni wọn sọ pe dandan ni ki gomina waa ba awọn sọrọ, gomina si wa, lasiko ti wọn n beere ibeere lọwọ rẹ, ti iyẹn si n dahun ni awọn kan lara wọn bẹrẹ si i sọ okuta si gomina.

Bi awọn kan ṣe fa ada yọ lawọn mi-in yọ olonde jade, ti gbogbo awọn eeyan si n sare kaakiri.

Bayii ni awọn ẹṣọ gomina gba a niyanju lati kuro nibẹ, bi o ṣe gbera lawọn ọmọ yii bẹrẹ si i ju okuta lu gbogbo mọto to tẹle gomina wa.

Gbogbo mọto Oyetọla, awọn kọmisanna, awọn oludamọran pataki, awọn oṣiṣẹ rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ to wa pelu rẹ ni wọn fọ gilaasi wọn, ti ọpọlọpọ awọn eeyan si fara pa.

Lẹyin eyi ni wọn tun bẹrẹ si i sun taya loju titi, wọn n fi agidi wọ ile-epo to wa nitosi, ti wọn si n gba epo bẹntiroolu lati fi dana soju titi.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori obinrin, Danladi gun ọrẹ rẹ pa l’Ode-Aye

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Money Danladi, ni wọn ti fẹsun kan …

5 comments

  1. that’s what he deserve even many governors are joined the protester why oyetola refuse to contribute to endsars protest. instead he used to took another route to his office which is oba aderemi way bye pass (onababaona). oyetola is acting governor he has no action.

  2. Àṣejù t’ife wọ ọrọ iwode yi.awon ọdọ yi t’ifẹ fi àṣejù bọ kolode.omotanba mu kanfi jofin

  3. E o so biwon se yinbon fun awon ogo ola mo ooo e beru Olorun ooo

  4. Oro to wa ni’le bayi ti fihan wipe o tl ni owo kan oselu ati etanu ninu.l’oju temi iwa odale pataoata gbaa ni. Nitori idi eyi more Baba Oyetola ki won dakun f’owo w’onun

  5. Abdulazeez omotayo

    Awon oloselu ti towo bo pro naa, kolohun lawa

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: