Awọn tọọgi da ipolongo ibo Jẹgẹdẹ ru l’Ọwọ, eeyan marun-un lo fara pa

Oluṣẹyẹ Iyiade Akure

Eto ipolongo ibo ẹgbẹ PDP ti wọn fẹẹ ṣe niluu Ipele, nijọba ibilẹ Ọwọ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo fori sanpọn latari rogbodiyankan to bẹ silẹ lọjọ naa.

ALAROYE gbọ lati ẹnu awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn pe bi Jẹgẹdẹ atawọn alatilẹyin rẹ ṣe wọ ilu ọhun ti wọn si ni ki awọn lọọ ki ọba wọn lawọn tọọgi kan ti wọn ni wọn n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ APC dena de wọn,  ti wọn ko si fẹ ki wọn kọja.

Ibi ti wọn ti n fa ọrọ yii mọ ara wọn lọwọ ni rogbodiyan ti bẹ silẹ, ninu eyi tawọn ọmọ ẹgbẹ PDP mẹta ti fara pa yannayanna.

Awọn ọlọpaa atawọn Sifu Difẹnsi to wa nitosi ni wọn fi agidi tu awọn janduku naa ka, ti wọn si sare gbe awọn to fara pa lọ sile-iwosan fun itọju gẹgẹ bo ṣe sọ.

Idi ree ti ẹgbẹ PDP Ondo fi pariwo, ti wọn si n n kilọ fawọn ọmọ ẹgbẹ APC ki wọn tete jawọ ninu akọlu ti wọn n ṣe si wọn.

Ẹgbẹ ọhun tun rọ ọga ọlọpaa patapata nilẹ Naijiria lati ba awọn ọmọ abẹ rẹ sọrọ ki wọn yago fun ojuṣaaju ṣiṣe saaju ati lẹyin eto idibo to n bọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Leave a Reply