Awọn tọọgi kọ lu awọn ọmọ ẹgbẹ APC to n ṣatilẹyin fun Tinubu n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nnkan ko rọgbọ fun diẹ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), to kopa ninu iwọde ti wọn ṣe lati ṣatilẹyin fun oludije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, n’Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan lawọn tọọgi ọhun ya lu awọn to kopa ninu iwọde naa, ti wọn si fi koboko ati pankẹrẹ dara si wọn lara ni Iyana Labiran, lọna Oje.

Ọpọ eeyan ni wọn lo fara pa ninu ikọlu naa, ti wọn si yara gbe wọn lọ sileewosan ti wọn ko darukọ fun itọju.

Alamoojuto awọn ibudokọ ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Mukaila Lamidi, ẹni tọpọ eeyan mọ si Auxilliary ni wọn lo ko awọn tọọgi naa sodi, oun funra ẹ ni wọn lo wa eyi to ṣaaju ninu awọn bii mẹẹẹdogun to kọwọọrin ṣe ikọlu naa.

 

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ, Ọgbẹni Adeolu Adelani ṣalaye pe “Awọn Teslim Fọlarin ti lọ niwaju, ẹyin lawa wa ni tiwa, ti awọn tọọgi yẹn fi yọ si wa lojiji, ti wọn si bẹrẹ si i ko pankẹrẹ ati koboko bo awọn eeyan.

“Bi mo ṣe ri i pe wọn ti n lu awọn eeyan ni mo yara ṣi fila Tinubu ti mo de sori, ti mo fi sa asala fun ẹmi mi. Bi gbogbo awọn eeyan mi ta a jọ bẹrẹ iwọde yẹn laaarọ ṣe sa asala fun ẹmi ara wa niyẹn, ti ko sẹni to mọ ibi ti ẹni keji gba lọ mọ”.

Bii omi lero pọ rẹpẹtẹ nibi eto iwọde naa. Ile-ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ to wa l’Oke-Ado, n’Ibadan, ni wọn fipade si lati bẹrẹ iwọde onimiliọnu kan eeyan ọhun.

Lati nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, si ni sẹkiteriati ẹgbẹ oṣelu naa to wa laduugbo Oke-Ado, n’Ibadan, ko ti gbero mọ, ti wọn n lulu, ti wọn n jo, fun igbaradi iwọde naa.

Irin ọhun, ti wọn bẹrẹ lati Oke-Ado, ni wọn ba lọ si awọn adugbo bii Mapo, Agodi-Gate, Mọkọla, ki wọn too fi adagba ẹ rọ si Oke-Ado ti wọn ti bẹrẹ irinajo naa.

Gbogbo eekan ninu ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ nipinlẹ Ọyọ lo kopa ninu eto ọhun, bẹrẹ latori Ọgbẹni Isaac Ọmọdewu ti i ṣe alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ yii pẹlu awọn igbimọ alakooso ijọba rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Iwọde ọhun ko yọ awọn to n dupo oṣelu kan tabi omi-in lorukọ ẹgbẹ naa nipinlẹ yii silẹ. Lara wọn ni Sẹnitọ Teslim Fọlarin to n dupo gomina atawọn ti wọn n dupo sẹnitọ bii Alhaji Yunus Akintunde,  Amofin Sarafadeen ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn orin ati ilu alujo ti Agba ọjẹ Olorin Fuji nni, Alhaji Rasheed Ayinde (Merenge), fi n da wọn laraya lori irin naa ko jẹ ki wọn mọ ala irin ti wọn n rin ninu oorun ọsan gangan naa.

Akitiyan ALAROYE lati gbọ awijare Auxilliary, ati igbiyanju wa lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lẹnu SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko seso rere pẹlu bi awọn mejeeji ko ṣe gbe awọn ipe ti akọroyin wa pe wọn.

Leave a Reply