Awọn tọọgi kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde SARS l’Oṣogbo, wọn ṣa wọn ladaa yannayanna

Florence Babaṣọla

Ọrọ ifẹhonuhan tako SARS niluu Oṣogbo, di wahala laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, nigba ti awọn tọọgi kan ya bo wọn, ti wọn si bẹrẹ si i ṣa wọn ladaa.

Orita Ọlaiya ni wahala ti bẹrẹ, ti gbogbo awọn olugbe agbegbe naa si n sa kijokijo kaakiri fun ẹmi wọn.

Mẹta lara awọn ọmọ to n fi ẹhonu han yii ni ada ba, ọkan lara wọn, Ọlatokun Oloyede, si ṣeṣe lori.

Bi awọn tọọgi ọhun ṣe pitu ọwọ wọn tan, ti wọn si lọ, lawọn olufẹhonuhan ọhun pada bọ sita lọpọ yanturu si i, ti wọn si pinnu pe wahala ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

Leave a Reply

%d bloggers like this: