Ọlawale Ajao, Ibadan
Ba a ṣe n wi yii, ẹka ti wọn ti n tọju awọn alailera ti wọn nilo itọju pajawiri lawọn oṣiṣẹ ẹṣọ Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ wa, nitori bi awọn tọọgi ṣe dojú ija kọ wọn, tí wọn sì ṣe ọpọ nínú wọn pẹlu awọn ọlọpaa leṣe rẹ́kẹrẹ̀kẹ.
Ẹsẹ-kan-aye ẹse-kan-ọrun ni mẹrin ninu awọn ẹṣọ Àmọ̀tẹ́kùn wa bayii, pẹlu bi awọn ẹruuku ṣe fi ada, aake ati àpólà igi lù wọn ṣe leṣe.
Ninu laasigbo ti awọn ipata ọmọkunrin agbegbe Ọdẹ́yalé, nijọba ibilẹ Ọ̀nà-Àrà, n’Ibadan, dá silẹ nijanba nla ọhun ti ṣe awọn agbofinro yii.
Nigba to n fìdí iṣẹlẹ yii múlẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, Oludari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, ṣalaye pe awọn ọmọ iṣọta kan ni wọn n da agbegbe Ọdẹ́yalé, n’Ibadan, ru, ti ẹgbẹ awọn lanlọọdu agbegbe naa fi pe ileeṣẹ Amọtẹkun ni ipe pajawiri fún ìrànlọ́wọ́.
Ṣugbọn kàkà kí awọn tọọgi wọnyi sa lọ nigba ti awọn Amọtẹkun dé, niṣe ni wọn dojú ija kọ awọn agbofinro naa, ti wọn sì jọ n yinbọn mọra wọn.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, bi awọn olugbe agbegbe yii ṣe pé àwọn Amọtẹkun naa ni wọn pe awọn ọlọpaa, ikọ awọn agbofinro mejeeji yii ni wọn si sa ipa wọn lati paná rogbodiyan ọhun, ṣugbọn omi pọ ju ọkà lọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo, bi awọn tọọgi wọnyi ṣe ṣe awọn Amọtẹkun léṣe, bẹẹ ni wọn ko jẹ káwọn ọlọpaa paapaa faraare lọ.
Akitiyan akọroyin wa lati gbọ tẹnu SP Olugbenga Fadeyi ti i ṣe Alukoro fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lori iṣẹlẹ yii ko seso rere titi ta a fi parí akojọ iroyin yii.
Ajagun-fẹyinti Ọlayanju ti i ṣe ọga awọn Amọtẹkun ipinlẹ yii ti fìdí ẹ̀ múlẹ pe ẹka itọju awọn ailailera pajawiri, nileewosan UCH, n’Ibadan, lawọn oṣiṣẹ Amọtẹkun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti wọn fara pa ju lọ ninu iṣẹlẹ yii wa titi ta fi pari akojọ iroyin yii.