Awọn tọọgi ya bo sẹkiteriati APC l’Ọṣun, alubami ni wọn lu awọn ọmọ ẹgbẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọrọ di bo o lọ o ya lọna lonii ni olu-ile ẹgbẹ oṣelu APC to wa ni Ogo-Oluwa niluu Oṣogbo nigba ti awọn tọọgi kan ya wọbẹ, ti wọn si n lu awọn ọmọ ẹgbẹ nilukulu.

Nnkan bii aago mẹwaa aarọ ni wahala naa bẹrẹ, gbogbo agbegbe naa lo si gbona janjan titi di nnkan bii aago marun aabọ irọlẹ.

Abala kan ninu ẹgbẹ naa, iyẹn The Oṣun Progressives (TOP) ni wọn ya lọ si sẹkiteriati naa lati lọọ ri awọn ọmọ igbimọ ti awọn alakoso ẹgbẹ naa lapapọ ran wa si Ọṣun lati gbọ oniruuru ẹsun yo ṣuyọ lasiko idibo wọọdu ti wọn ṣe kọja.

Lati gbogbo ijọba ibilẹ ni awọn ọmọ ẹgbẹ TOP ti mu iwe ẹsun wa, ti awọn ọmọ igbimọ naa si n da wọn lohun lẹyọkọọkan.

Saa deede la gbọ pe awọn tọọgi kan ya wọle, ti wọn si bẹrẹ si i ko igbaju-igbamu bo awọn TOP. Ohun ti awọn TOP n sọ ni pe fila ti wọn kọ Oyetọla si lara lawọn tọọgi naa de sori, ati pe ijọba lo ran wọn wa lati dabaruu gbigbọ ẹsun naa.

Laaarin nnkan bii ogun iṣẹju ni wahala naa fi ṣẹlẹ, ṣugbọn agbara awọn TOP le ju ti awọn tọọgi ọhun lọ, alaafia si jọba lẹyin ti wọn le awọn tọọgi naa lọ tan.

Lẹyin eyi ni alaga igbimọ, Ambassador Obed Wadzain, bọ sita lati ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ, o ṣeleri fun wọn pe igbimọ oun ko ni i ṣojuṣaju ẹnikẹni, o ni gbogbo iwe ẹsun ti awọn ba gba lawọn yoo gbọ lẹyọkọọkan lai fi epo bọ iỵọ ninu.

Obed ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati gba alaafia laaye, o ni ko si ọmọ igbimọ to ni aayo kankan nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni iṣọkan ati idagbasoke ẹgbẹ lo jẹ awọn logun.

Bayii ni wọn tun bẹrẹ ṣiṣe ayẹwo awọn iwe ẹsun naa nijọba ibilẹ si ijọba ibilẹ, nigba to di nnkan bii aago marun-un irọlẹ ni irọkẹkẹ wahala tun ṣẹlẹ ninu sẹkiteriaati naa.

Bi wọn ṣe n ju okuta, ni wọn n ju aga, bi wọn ṣe n ju igi, ni piọ-wọta n fo loju ofurufu, nigba ti ọrọ naa ko loju mọ ni awọn ọlọpaa fẹyin pọn awọn ọmọ igbimọ naa wọnuu mọto, ti wọn si n yinbọn soke lakọlakọ lati tu awọn eeyan naa ka.

Alaroye ba alaga TOP nipinlẹ Ọṣun, Alagba Adebiyi Adelọwọ sọrọ ko too di pe wahala ẹlẹẹkeji bẹrẹ, o ni awọn tọọgi kan ni wọn wa lati da eto naa ru laaarọ, ṣugbọn ohun gbogbo pada bọ sipo lẹyin-ọ-rẹyin.

O ni iwe ẹsun mejilelọgbọn ni awọn igbimọ naa kọkọ gba, ṣugbọn wọn ṣi n gba iwe ẹsun lọ. Lai fi ti wahala yii ṣe, Adelọwọ sọ pe ireti ijawe olubori wa fun ẹgbẹ naa ninu idibo gomina lọdun to n bọ, gbogbo ohun to gba lawọn yoo si fun un nitori oniluu ko nii fẹ ko tu.

Amọ ṣa, Gomina Oyetọla ti ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun lati gba alaafia laaye, o ni ko le si idagbasoke nibi ti itaporogan ba ti n waye ati pe wọn ko gbọdọ faaye gba ẹgbẹ alatako lati ri aarin wọn.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ismail Omipidan, fi sita, o ni ipinlẹ alaafia ni gbogbo eeyan mọ ipinlẹ Ọṣun mọ, oun ko si nii faaye gba ẹnikẹni lati da omi alaafia ipinlẹ yii ru.

Oyetọla wa ke si awọn agbofinro lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn si ri i pe alaafia pada sipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply