Ọlawale Ajao, Ibadan
Ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Ìgbòho Òòṣà), ti woye pe awọn ọdaran Fúlàní ti oun n gbogun ti lati fi ilẹ Oodua silẹ ni wọn dana sun ile oun. Ṣugbọn ọrọ naa lọwọ awọn ọmọ Yorùbá nínú.
Lọsan-an ana lo sọrọ náà fawọn oniroyin lẹyin ti awọn ọdaran kan ti wọn kò tí ì foju han dana sun ile e.
“Yoruba bọ, wọn ni biku ile o ba pa ni, tode o le pa ni. Ti ko bá si awọn ọmọ Yorùbá kan níbẹ ti wọn lẹdi apo pọ mọ awọn Fúlàní, ko sí bí wọn ṣe fẹẹ mọ ile mi.
“Wọn ní bó wọn ṣe dé ni won kọkọ yinbọn ko tóo di pe wọn ki ina bọ ile mi ki wọn too sa lọ.
“Ṣugbọn bi wọn ba fẹẹ fi ara wọn hàn bi alagbara, dipo ti wọn fi lọ sí ile ti mo n gbe tẹle, ile mi ti mo n gbe bayii gan-an lo yẹ ki wọn wà, ki wọn sì wà lójú mọmọ ki gbogbo ayé ríran rójú wọn ka lè mọ pe ọkunrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni wọn.”
O ni ko sẹni to fara pa ninu iṣẹlẹ ọhún nitori oun ko gbe inu ile naa mọ.
Ṣaaju lagbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi ti ṣalaye ọna ti wọn gba dana sun ile Sunday Ìgbòho, o ni lọ́gànjọ́ oru lawọn ọbayejẹ ẹda ọhun sáré wọ ile ti Igboho n gbe tẹlẹ laduugbo Sókà, n’Ibadan, ti wọn sì da ibọn bolẹ lọpọlọpọ igba ki wọn too ki iná bọlé ọhun, ti wọn sì sa lọ.
O ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa ati pe laipẹ lọwọ awọn agbofinro yóò tẹ awọn ọdaran to huwa bàsèjẹ́ náà.