Lọla Ojo
Gomina ipinlẹ Cross Rivers tẹlẹ, Donald Duke, ti kegbare pe aworan oun ni awọn eeyan to n kọ nnkan lọlokan-o-jọkan nipa itan igbesi aye oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu, n lo gẹgẹ bii aworan igba ewe ọkunrin naa. O ni oun loun wa ninu fọto naa, ki i ṣe oludije funpo aarẹ yii.
Gomina atijọ yii sọrọ naa fawọn olootu iweeroyin lasiko ipade kan ti ajọ kan to n jẹ Front Fort Initiative ati MacArthur Foundation gbe kalẹ, eyi to waye niluu Eko. Nibẹ lo ti sọ pe oun loun wa ninu aworan yii, ki i ṣe Aṣiwaju Bọla Tinubu.
O to ọjọ meta ti wọn ti n gbe aworan naa kiri ninu awọn akanṣe akojọpọ itan nipa igbesi aye Tinubu, ti wọn si n sọ pe igba ti oloṣelu naa wa ni sango ode ni.
Awọn afihan yii waye nitori bi awọn kan ṣe n pariwo pe ayederu ni ọjọ ori ọkunrin oloṣelu yii, ileewe to lọ ati ọmọ ilu ti i ṣe. Eyi lo mu ki wọn maa gbe awọn apilẹkọ yii jade lati ṣalaye igba to ṣe ewe awọn ileewe ti ọkunrin naa lọ atawọn irinajo rẹ nidii oṣelu.
Aimọye igba ni awọn to n polongo ibo fun Tinubu, awọn ileeṣẹ tẹlifiṣan lọlọkan-o-jọkan, ori ẹrọ ayelujara, to fi mọ tẹlifiṣan Aṣiwaju paapaa, iyẹn TVC, ni wọn ti lo aworan yii ninu awọn akanṣe itan nipa igbesi aye ọkunrin oloṣelu naa, ti wọn si n gbe aworan yii si i gẹgẹ bii igba to wa ni ọdọ.
Aworan ọhun ni ibi ti ọdọmọkunrin kan to fi igo dudu soju ti jokoo, to ki ika re bọ ara wọn ọwọ re pọ, Eyi ni awọn eeyan naa n tọka si gẹgẹ bii igba ti Tinubu wa lọdọọ.
Ṣugbọn alaye ti Duke ṣe pe oun loun wa ninu aworan naa ti fopin si gbogbo bi awọn eeyan ṣe n lo o pe igba ti Tinubu wa ni kekere ni.
Ọpọlọpọ eeyan lo ti n bu ẹnu atẹ lu awọn ti wọn gbe aworan ti ki i ṣe ti ọkunrin naa jade, ti wọn si n sọ pe oun ni, wọn ni ko si ohun ti awọn eeyan ko le ṣe nitori oṣelu.