Gbogbo eyi ti a n wi dun, ẹ tọju Tinubu o!

Fidio kan n ja ran-in ran-in kaakiri ilẹ yii bayii, iyẹn fidio kan ti Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ti da ede Hausa palẹ. To si sọ fawọn ti wọn n ba a sọrọ pe oun ti kilọ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu pe agbara ati ilera rẹ ko gbe wahala to tun fẹẹ maa ṣe yii, ko lọọ tọju ara ẹ, ko fi ipo aarẹ silẹ fawọn ọmọde, koun maa tọ wọn sọna. O ni ninu oṣu Karun-un ọdun, ki wọn too dibo abẹle ẹgbẹ APC loun ti ṣekilọ naa f’Aṣiwaju, awọn alatako lo tun ju fidio naa sita bayii, o si daju pe nitori awọn ohun to n ṣẹlẹ si Tinubu lawọn ode to n lọ kaakiri ni. Ọpọ ibi ti Tinubu n lọ bayii lo n han pe ilera rẹ ko fi bẹẹ daa to, bo tilẹ jẹ awọn ti wọn yi i ka, atoun funra rẹ n sọ pe irọ ni, ko ri bẹẹ. Nigba ti eeyan ba bọ silẹ ninu mọto, to n fi dugbẹdugbẹ bii ẹni to mu nnkan, to n pogira nibi ti ilẹ ba ti ga diẹ, tawọn eeyan n rọ ọ mu bii eegun, dajudaju nnkan n ṣe e lagọọ ara ni. Nigba ti eeyan ba jade si gbangba, to fẹẹ bawọn eeyan sọrọ, ti ọrọ naa de agbedemeji to daru mọ tọhun loju, to bẹrẹ si i sọ ede ti awọn to n ba sọrọ ko gbọ, to n sọ ohun ti ko ba eto ti wọn n ṣe mu, ko ṣẹṣẹ digba ti wọn ba sọ pe nnkan n ṣe iru ẹni bẹẹ ki awọn to wa nibẹ too mọ pe tọhun ko gbadun loootọ. Ko si tabi ṣugbọn nibẹ pe alaafia ko fi bẹẹ to fun Aṣiwaju, bẹẹ ni eyi ki i ṣe lati ba a jẹ. Ara lile loogun ọrọ, bi ara ko ba si ya, inu ko le dun, nidii eyi lo ṣe jẹ pe ko si ohun ti ẹda gbọdọ kọkọ wa laye yii ju ilera lọ. Ṣugbọn ọpọ awọn oloṣelu Naijiria ko daa, ika lo pọ ju ninu wọn. Wọn yoo koriira ẹni ti wọn n tẹle debii pe wọn ko ni i kọ ko ku, wọn ko ni i bikita bi ilera rẹ ti ri, ohun ti wọn fẹẹ gba ti tọhun ba depo lo wa lọkan wọn, wọn yoo si maa fọkan sọ pe bi tọhun ba fẹẹ ku ko ṣaa jọwọ ko depo yii na, ko si ṣe ohun to fẹẹ ṣe fun awọn fawọn. Ika ni wọn, wọn ko laaanu, awọn to n fi oṣelu ṣiṣẹ ni Naijiria, ọna ọfun ọna ọrun ni. Ko si ohun ti wọn ko le ṣe lati depo, tabi lati ri i pe ẹni ti awọn fẹ depo, bẹẹ ni ki i ṣe nitori ifẹ ilu, tabi ifẹ ẹni ti wọn n ti siwaju, nitori ifẹ tara wọn nikan ni. Awọn ti wọn n tẹle Aṣiwaju yii, nigba ti ẹnikẹni ba sọ pe ara baba naa ko ma ya, tabi pe baba naa ti dagba, kia ni wọn yoo ti ta pẹẹrẹ, wọn yoo ni ṣe o fẹẹ lọọ lagi, tabi fọ apata nile ijọba ni, ṣebi ironu ẹ lasan laraalu nilo, ko kan maa ronu fun wọn lasan, ko si maa sọ ohun ti wọn yoo ṣe ni.  Nibi ti laakaye awọn yii ṣiṣẹ de ree. Ọpọlọ wọn o sọ fun wọn pe ẹni ti yoo ba ronu daadaa, ara rẹ gbọdọ ya, ko si pe perepere. Wọn ko rẹni sọ fun wọn pe agbara ti ẹda fi n ronu arojinlẹ ju eyi ti wọn fi n fọ apata tabi lagi lọ. Nibi ironu ni iṣẹ wa, iṣan lasan ni alagbara ni, bi ko ba lero lori, ofo lasan ni, eyi lo ṣe jẹ awọn to ba ni laakaye, to ni ọpọlọ, lo n ran alagbara niṣẹ kiri! Bi o ba lagbara ti o ko lọgbọn, alagbara-ma-mero ni wọn n pe iru ẹni bẹẹ, nitori ọlọpọlọ-pipe gan-an ni alagbara. Bi iba lasan ba wọ eniyan lara, njẹ tọhun ha le ronu gidi bi! Ka ma ti i waa sọ aisan ti n ko laakaye ẹni lọ. Nigba ti Aṣiwaju ba fẹẹ sọrọ APC to jẹ ẹgbẹ tirẹ, to jẹ ẹgbẹ to fẹẹ gbe e wọle, to ki adura mọlẹ, to bẹrẹ si i ṣe e fun PDP, ẹgbẹ ti ko fẹ ko wọle, ẹgbẹ alatako, ki lo ṣẹlẹ si iru ọpọlọ bẹẹ yẹn. Nigba ti Aṣiwaju ba n sọrọ lọ, to de aarin meji to daku, ki lo ṣẹlẹ siru ọpọlọ bẹẹ yẹn! Nigba ti Aṣiwaju ba n lọ sipade nla, to gbiyanju lati da rin, ṣugbọn to bẹrẹ si i fi dugbẹdugbẹ debii pe ṣe lawọn eeyan pada waa rọ ọ mu, ti wọn fẹgbẹ pọn ọn debi to n lọ, njẹ o ha raaye lo ọpọlọ naa bo ti ṣe fẹẹ lo o bi? Afihan pe nnkan ko ri bo ti yẹ ko ri ree, ilera to pe ko si fun Aṣiwaju wa. Ipo olori ijọba Naijiria ki i ṣe eyi ti eeyan n fi aabọ ara ṣe, wahala ọjọ diẹ ni wọn yoo fi pa tọhun! Ere wo ni yoo waa jẹ fun ẹnikẹni, ti Tinubu ba wọle ti ohunkohun ṣe e laarin ọjọ diẹ, ti wọn ni ko gba ilu oyinbo lọ fọjọ pipẹ, ko lọọ sinmi, ṣebi ohun ti a ko fẹ ko ṣẹlẹ naa ni yoo pada ṣẹlẹ, Ọlọrun ma jẹ a ri i. Bẹẹ, ọpọ anfaani lo wa ti Tinubu le ṣe fun gbogbo aye, ṣugbọn bi ẹmi ba wa, ti ara ẹni si pe perepere ni. Gbogbo eyi ti a n wi dun, ẹ tọju Aṣiwaju Bọla Tinubu, kinni kan ko gbọdọ ṣe e o. Koun naa tọju ara ẹ, nitori ẹmi o laarọ! Ẹni wa laye laraaye n ri, aye ki i ranti ẹni to ba ti ba tirẹ lọ. Ẹda gbọdọ tọju ara ẹ, ka yẹra fun ohun to le ko wahala ba okun ẹmi ẹni. Ka jinna sejo ta o bẹ lori, iku to ba fẹẹ pa ni, aa jinna si i ni.

 

Leave a Reply