Aworan ti wọn n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara ki i ṣe ọmọ temi o – Ọọni

Florence Babasola, Oṣogbo

Arole Oodua, to tun jẹ Ọọni ti Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti sọ pe ki i ṣe aworan ọmọ tuntun tiyawo oun, Olori Ṣilẹkunọla, ṣẹṣẹ bi lawọn eeyan n gbe kaakiri ori ikanni ayelujara.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin laafin Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita lo ti ṣalaye pe Ọọni nikan lo laṣẹ lati gbe aworan ọmọ rẹ sita, ko si ti i ṣe bẹẹ titi di asiko yii.

Ọlafare ṣalaye pe oniruuru etutu lo gbọdọ waye ko too di pe wọn yoo fi oju ọmọ tuntun naa han faraye ri, gbogbo eleyii ni wọn si n ṣe lọwọ nibamu pẹlu aṣa ati iṣe ilẹ Ifẹ.

O ni aworan ọmọdekunrin ti wọn n gbe kaakiri naa ki i ṣe ti ọmọ Ọọni, o si rọ gbogbo awọn oniroyin lati maa wadii ohun gbogbo daju ki wọn to maa gbe e jade.

Leave a Reply