Aye ti bajẹ o, ẹ wo ohun t’ọmọbinrin yii ṣe nitori owo ti ko si lọwọ rẹ

Monisọla Saka

Obinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) kan, Sofia Nkwo, ti n ka boroboro lọdọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Delta, nitori ọmọ bibi inu ẹ, ọmọ ọdun kan, to ṣe ẹmi ẹ lofo.

CP Abaniwọnda Olufẹmi, ti i ṣe kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Delta, lo sọrọ ọhun di mimọ lasiko ti wọn n foju awọn afurasi ọdaran hande lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Asaba.

O ni, “Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn mu ẹjọ pe wọn pa ọmọde kan wa si teṣan ọlọpaa Oleh. Afurasi ọhun, Sofia Nkwor, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to wa lati ijọba ibilẹ Isoko, ni wọn lo lọọ ju ọmọ ẹ ọkunrin, ọmọ ọdun kan ati oṣu mẹrin sinu kanga kan to wa lagbegbe Araya, mijọba ibilẹ Guusu Isoko, nipinlẹ Delta.

“Awọn ọmọ keekeeke ti wọn lọọ ṣere nibi igi kan ti ko jinna sidii kanga ọhun ni wọn ri oku ọmọ to ti lefoo soju omi ọhun. Loju-ẹsẹ lọwọ ti tẹ iya ọmọ naa, iyẹn Sofia Nkwor. O ni lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, loun ti ju ọmọ naa sibẹ”.

Abaniwọnda ṣalaye siwaju si i pe awijare obinrin to pa ọmọ ẹ yii ni pe oun ko lagbara lati tọju ẹ mọ, nitori ko si owo lọwọ oun, oun ko si niṣẹ kankan lọwọ, nigba ti baba toun bi i fun naa ko si tun gba a lo jẹ ki oun ro gbogbo ẹ papọ, toun ṣe lọọ ju u sinu kanga laaye.

O ni lẹyin toun ti fun un lọyan fungba diẹ, ti awọn mọlẹbi oun si ti da itọju ọmọ naa da oun, pẹlu bi gbogbo nnkan tun ṣe le koko nitori ọrọ aje to dẹnu kọlẹ, loun ṣe ro o pin, ti oun gbẹmi ọmọ ọhun.

Leave a Reply